Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Gbinrin-gbinrin ni agbegbe Lotto, loju ọna marosẹ Eko s’Ibadan, kan lọjọ Ẹti, Furaidee ọjọ kẹrin, oṣu kẹfa yii, latari tirela to padanu ijanu rẹ, to si lọọ tẹ awọn obinrin meji kan ti wọn n kiri ọja pa.
Nnkan bii aago mẹta-aabọ ọsan ọjọ naa ni ijamba yii waye, nigba ti tirela ti nọmba ẹ jẹ SMK 82 XX, padanu ijanu ẹ, to kuro loju ọna to n gba, to si bẹrẹ si i ṣe balabala kiri oju popo, titi to fi kọ lu awọn obinrin meji to n kiri ọja naa, to si pa wọn sibẹ loju esẹ.
Alukoro TRACE, Babatunde Akinbiyi, to fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, sọ pe awọn to ṣoju wọn ṣalaye pe Eko ni tirela naa n lọ ko too ko si wahala.
Wọn ni yatọ sawọn to tẹ pa yii, o tun ṣe awọn eeyan mi-in naa leṣe gidi.
Awọn TRACE ti gbe oku mejeeji lọ si mọṣuari Idẹra, ni Ṣagamu, wọn si ko awọn to ṣeṣe lọ sileewosan Famobis, ni Mowe.
Teṣan ọlọpaa Mowe ni wọn tọju awakọ to wa tirela naa si, nibi to ti n ṣalaye ẹnu rẹ fun wọn, tirela to fi daran naa si wa nibẹ pẹlu.