Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Tirela ti tẹ ọkan ninu awọn oṣiṣẹ alaabo ojupopo ti wọn n pe ni FRSC pa loju ọna to lọ si Ijẹbu-Ode lati Ṣagamu, lasiko tọkunrin naa n ṣiṣẹ oojọ rẹ lọwọ.
Ọga agba FRSC nipinlẹ Ogun, Kọmandanti Ahmed Umar, fiṣẹlẹ yii lede l’Ọjọruu, ọjọ kejilelogun, oṣu kejila, ọdun 2021, pẹlu alaye pe Mọnde, ogunjọ, oṣu kejila, niṣẹlẹ ọhun waye.
Nigba to n ṣalaye lẹkun-un rẹrẹ, Umar sọ ọ di mimọ pe aibikita pẹlu iwakuwa ọkọ lo fa a ti ẹni to wa tirela naa fi lọọ gba oṣiṣẹ awọn.
O ni niṣe lawọn oṣiṣẹ FRSC naa duro wọn jẹẹjẹ nibi ti wọn ti n ṣiṣẹ loju popo, bi awakọ to n wa iwakuwa naa ṣe padanu ọwọ ọkọ niyẹn, lo ba kọ lu ọkan ninu awọn oṣiṣẹ alaabo to duro jẹẹjẹ, o si gba a naa to jẹ niṣe lo gbe e saarin tirela yii ati ọkọ FRSC ti wọn fi n ṣiṣẹ.
Bi eyi ṣe ṣẹlẹ ni ọfisa naa ku gẹgẹ bi Umar ṣe wi, ikeji rẹ ti wọn si jọ wa nibẹ fara pa.
Awakọ to wa tirela naa ko duro bo ti gba wọn tan, wọn ni niṣe lo sa lọ bo ti ri ohun to ṣẹlẹ.
Ṣugbọn awọn awakọ tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn bẹrẹ si i le e, bẹẹ lawọn ọlọkada to wa nitosi naa darapọ mọ wọn, wọn le e gidi.
Nigba to to asiko kan, awakọ naa bọ silẹ ninu tirela rẹ, o fi mọto ọhun silẹ o si bẹrẹ si i fẹsẹ sare lọ, ṣugbọn awọn to n le e ko pada, wọn ri i mu dandan wọn si fa a fọlọpaa gẹgẹ bi Umar ṣe wi.
Ni ti ọfisa keji to fara pa, ileewosan lo ṣi wa lasiko ta a n kọ iroyin yii, to n gbatọju lọwọ.