Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Aago meje aarọ ku ogun iṣẹju ni ijamba mọto kan ṣẹlẹ loju ọna marosẹ Eko s’Ibadan, lagbegbe ileepo F.O. Iyẹn lọjọ Satide, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kẹjọ. Tirela kan to ko okuta lo da wahala silẹ, ọpọlọpọ okuta to da soju ọna yii lo fa ijamba fun mọto mi-in, ohun to si fa iku awọn baale ile meji niyẹn.
Gẹgẹ bi FRSC ati TRACE ṣe fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, wọn ni mọto mẹta niṣẹlẹ yii kan, awọn naa ni Kia Rio to ni nọmba RBC 108 AE, Volkswagen Golf to ni nọmba GWA 114 BC ati Mẹsidiisi ti nọmba ẹ jẹ BDG 757 GF.
Awọn ti iṣẹlẹ yii ṣoju wọn ko too di pe awọn ẹṣọ alaabo de ṣalaye pe tirela kan lo ti kọkọ danu sagbegbe naa ti okuta to ko sinu si pọ nilẹ. Ko sẹni to mọ bi tirela ọhun ṣe kuro nibẹ, ṣugbọn awọn okuta to danu wa lapa ibi to ṣubu si ọhun, o si pọ gan-an.
Wọn ni okuta naa lo fa ijamba ọkọ lafẹmọju, ti awọn ọkọ mẹta fi kọ lu ara wọn, ti ọkunrin meji si jẹ alaisi ninu awọn to wa ninu ọkọ mẹta ọhun.
Ile igbokuu-si Idẹra, ni Ṣagamu, ni wọn gbe awọn baale ile meji to ku naa lọ, wọn si gbe ẹni to fara ṣeṣe lọ sileewosan kan naa.
Eto ti bẹrẹ lati ko awọn okuta to kun titi naa kuro lasiko ti a n kọ iroyin yii, bẹẹ ni wọn ti ko awọn ọkọ to lasidẹnti naa lọ si teṣan ọlọpaa Ṣagamu.