Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kẹrin, ọdun 2021, lawọn ọkunrin mẹrin yii da tirela kan to ko fulawa Golden Penny lọna ni marosẹ Ṣagamu si Ijẹbu-Ode, ti wọn de dẹrẹba ọkọ naa atọmọ ẹyin ẹ lọwọ sẹyin, ti wọn tun fi sẹloteepu di wọn lẹnu pa ninu igbo ti wọn gbe wọn lọ.
Ọwọ ko tẹ wọn nigba naa, afi lọjọ karun-un, oṣu karun-un yii, ni wọn too bọ sọwọ awọn agbofinro.
Orukọ awọn mẹrin naa ni: Eze Anthony Sopruchukwu, Eze Chijioke Edeh, Ọlalekan Ayọdele Muritala ati Samuel Johnson.
Ohun ti ALAROYE gbọ latẹnu Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, ni pe ifisun wa pe awọn adigunjale da tirela kan ti nọmba ẹ jẹ ANG 57 LG lọna, beẹ apo fulawa ẹgbẹta (600) lo wa ninu ọkọ nla naa.
Wọn fi kun un pe Ahmed Tiamiyu ni awakọ tirela naa n jẹ, wọn ni niṣe lawọn adigunjale naa so ọwọ dẹrẹba yii ati tọmọ ẹyin ọkọ rẹ mọ ẹyin, ti wọn fi sẹloteepu lẹ ẹnu wọn pọ ninu igbo ti wọn gbe wọn lọ. Lẹyin naa ni wọn gbe tirela lọ pẹlu ẹru inu ẹ, ẹnikẹni ko si gburoo wọn rara mọ.
Pẹlu iwadii, awọn ọlọpaa ri ọkan mu ninu awọn ole naa n’Ikorodu lẹyin oṣu kan, mimu ti wọn mu un lo ṣatọna bi wọn ṣe ri awọn mẹta yooku mu.
Ninu ẹgbẹta apo fulawa ti wọn ko lọ, ọgọrun-un kan ati marundinlọgọrin (175) ni wọn ri ko pada ninu ile ikẹru-si olori ole naa, Eze Anthony.
Awọn ọlọpaa ti ni iṣẹ ṣi n tẹsiwaju lori awọn adigunjale yii, wọn ni gbogbo wọn ni yoo fimu kata ofin