Tiribuna, ẹ jẹ kidaajọ yin jẹ ootọ, ko si peye,  tẹ o ba fẹ ki… – Ẹgbẹ ajafẹtọọ ṣekilọ

Faith Adebọla

 Agbarijọ awọn ẹgbẹ ajafẹtọọ ọmọniyan kan, The International College of Democracy and Human Rights, eyi ti awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ bii ọgọta wa ninu rẹ ti ṣekilọ fun igbimọ onidaajọ ẹlẹni marun-un to n gbọ awuyewuye to su yọ nibi eto idibo sipo aarẹ to kọja, Presidential Election Petition Court (PEPC) pe oju ẹjọ ni ki wọn da, bẹjọ ba si ṣe lọ ni ki wọn da a, ki wọn jẹ ki idajọ wọn jẹ ootọ ati eyi to peye, tori ọrọ to le bi Ige to si le bi Adubi, to le da yanpọnyanrin silẹ ni bi idajọ wọn ba lọwọ kan ojooro ati abosi ninu.

Ẹgbẹ naa sọrọ yii ninu atẹjade kan ti wọn fi lede fawọn oniroyin niluu Enugu pe ojuṣe igbimọ yii ni lati ojulowo ibo kuro ninu ayederu, laarin esi idibo ti ajọ eleto idibo INEC kede rẹ lawọn ibudo idibo to din diẹ lẹgbẹrun lọna ọgọsan-an ti ibi ti waye, ki wọn si jẹ ki idajọ wọn ṣafihan koko inu ofin ilẹ wa, ko maṣe jẹ idajọ ti wọn gbe kari awọn aṣiṣe pẹẹpẹẹpẹẹ tawọn amofin n pe ni tẹkinikalitiisi (technicalties) lede oyinbo.

Wọn lọrọ iku ati iye lọrọ ẹjọ bii eyi, to tọ ki iwadii fẹsẹ rinlẹ lori ẹ, ki idajọ ododo ti yoo mu inu araalu dun di ṣẹlẹ.

Wọn tun parọwa pe ki ijọba atawọn abẹṣinkawọ wọn, awọn ajọ eleto aabo atawọn agbofinro gbogbo maṣe ṣayọjuran si idajọ igbimọ tiribuna yii, wọn o gbọdọ kọ ẹjọ ti wọn fẹẹ da le wọn lọwọ, wọn o si gbọdọ la le wọn lọwọ, ki wọn fun wọn lominira lati dajọ nibaamu pẹlu ofin ati ẹri-ọkan rere wọn.

Ẹgbẹ naa ni bi ajọ eleto idibo ilẹ wa ṣe faaye gba ojooro ati ibo yiyi ninu eto idibo to waye kọja ọhun buru jai, o buru ju iwa awọn ti wọn fibọn gbajọba lawọn orileede Niger, Chad ati Burkina-Faso lọ, bẹẹ ọtẹ ati eru lo maa n da ogun ati wahala silẹ.

Wọn kadii amọran wọn pẹlu akiyesi pe awọn aṣiṣe pẹẹpẹẹpẹẹ kan ti awọn ile-ẹjọ ilẹ wa kan ti gbe idajọ wọn ka latẹyinwa ti mu ipenija nla de ba eto idajọ ododo, to si ti mu ki awọn afurasi ọdaran to yẹ ki wọn maa gbatẹgun lọgba ẹwọn di ẹni to n yan fa-n-da laarin ilu, eyi ni wọn lo wa lara ohun ti iwa ajẹbanu, ikowojẹ ati awọn iwa ‘ko tọ’ mi-in ṣe n ran bii oorun lawujọ wa.

Leave a Reply