Tiyawo mi ba dagbere ọja, ile ale lo maa n lọ, mi o fẹ ẹ mọ – Hamzat

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Baale ile kan, Wasiu Hamzat Ọlatunji, ti sọ fun ile-ẹjọ kọkọ-kọkọ kan niluu Ilọrin, pe oun fẹẹ kọ iyawo oun, Kudirat silẹ. O ni obinrin naa maa n yan ale, ọrọ naa si buru debii pe to ba dagbere pe oun n lọ si ọja, ile ale lo maa n gba lọ.

L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹrinla, oṣu Kejila, ọdun yii, ni Abilekọ Kudirat Wasiu, gbe ọkọ rẹ lọ sile-ẹjọ pe ki adajọ tu igbeyawo ọdun mẹrindinlogun ti wọn ti wa papọ pẹlu ọmọ mẹta ti wọn bi fun ara wọn ka. Adajọ beere idi ti obinrin naa ṣe fẹẹ kọ ọkọ rẹ silẹ, o ni ko si ifẹ mọ naa ni.

Ọkọ iyawo sọ fun ile-ẹjọ pe ti ko ba fẹ oun mọ, oun gan-anko ṣe mọ, tori obinrin naa kundun ale yiyan. Ọkọ tẹsiwaju pe ọpọ igba ti Kudirat ba dagbere pe oun n lọ si ọja, ile ale ni yoo gba lọ, koda ale gan-an maa n waa fi ọkada gbe e nile awọn. Hamzat fi kun un pe ọkunrin to n yan lale naa n gbe e rinrin-ajo daadaa, o ni agbegbe Ẹyẹnkọrin, niluu Ilọrin, ni ale naa n gbe. O ni oun mọ eyi nitori oun tẹle e dele ale naa lọjọ kan ti iyawo oun dagbere ọja, ṣugbọn ko mọ pe oun n yọ tẹle e lẹyin, eyi to mu ki oun mọ ile ọkunrin to n yan iyawo oun lale. Baale ile yii ni eyi to buru ju ninu ọrọ naa ni bi ale iyawo oun ṣe maa n leri kiri pe oun yoo fẹ obinrin naa tọmọ-tọmọ mẹtẹẹta to wa lọwọ rẹ.

Nigba ti adajọ beere lọwọ iyawo pe ṣe Wasiu san owo-ori rẹ, o ni bẹẹ ni, o san ẹgbẹrun marun-un gẹgẹ bii owo-ori, ṣugbọn o ti gba owo naa pada ni pati lọjọ igbeyawo ọhun, ṣugbọn Wasiu sọ pe irọ ni obinrin yii n pa. Baale ile yii ni ẹgbẹrun mẹwaa loun san gẹgẹ bii owo-ori, oun ko si gba a pada.

Adajọ Lawal Ajibade ti ni ki Wasiu mu ẹlẹrii wa si kootu pe loootọ loun san ẹgbẹrun mẹwaa fun iyawo oun gẹgẹ bii owo-ori. Lẹyin eyi lo sun igbẹjọ si ọjọ kẹjọ, oṣu Keji, ọdun 2023.

 

Leave a Reply