Tobilọba ati Ṣeun maa fẹwọn ọdun mẹta jura, gbaju-ẹ ni wọn ṣe

Faith Adebọla, Eko

 

 

 

Ibanujẹ gidi ni Tobilọba Ibrahim Bakare ati Ṣeun Sikiru Alimi ba kuro ni kootu to n gbọ awọn ẹsun akanṣe n’Ikẹja, ipinlẹ Eko, l’Ọjọruu, Wẹsidee yii, afurasi ọdaran ni wọn ba de kootu, ṣugbọn ẹlẹwọn ni wọn ba kuro, ọdun mẹta gbako nile-ẹjọ ni ki wọn lọọ fi jẹwa lọhun-un.

Koda ti ki ibaa ṣe pe awọn afurasi ọdaran naa tete jẹwọ ẹṣẹ ni, boya fọpa-wọn lẹwọn wọn iba jẹ, tori ileeṣẹ ọkọ ofurufu mẹta ọtọọtọ ni wọn ṣe gbaju-ẹ fun, wọn ni wọn lu KLM ati Turkish Airline ni jibiti ẹgbẹrun lọna aadọtadinlẹgbẹrin dọla, (nnkan bii miliọnu ọọdunrun o din mẹẹẹdogun naira, (#285m), wọn si tun ṣe gbaju-ẹ ẹgbẹrun lọna ọgọfa miliọnu naira mi-in fun ileeṣẹ baalu British Airways.

Ṣugbọn nitori awọn afurasi ọdaran naa bẹbẹ lati fi awọn dukia wọn di ole ti wọn ja, ti wọn si rawọ ẹbẹ pe kile-ẹjọ ṣaanu awọn, kootu naa di ẹsun meje ti wọn ka si wọn lẹsẹ ku si meji pere, eyi lo si mu ki ijiya wọn mọ niwọnba.

Ajọ to n gbogun tiwa ibajẹ, jibiti lilu ati ṣiṣe owo mọkumọku, EFCC, lo pe awọn mejeeji lẹjọ, wọn si ti n ba igbẹjọ naa bọ lati oṣu ki-in-ni, ọdun yii.

Ninu alaye ti agbẹjọro fun olupẹjọ, Ọgbẹni Idris Mohammed, ṣe nile-ẹjọ, o ni niṣe lawọn ọdaran naa fi ọgbọnkọgbọn imọ kọmputa wọle sori atẹ ayelujara awọn ileeṣẹ ọkọ ofurufu mẹtẹẹta ti wọn lu ni jibiti, ni wọn ba n ka awọn lẹta imeeli tawọn ileeṣẹ naa n kọ, ati eyi ti wọn fi n gba owo, bi wọn ṣe bẹrẹ si i dari owo sinu asunwọn banki tara wọn niyẹn, ti alaati (alert) ba si ti dun gbọngan-un lori foonu wọn, owo ti wọle niyẹn, wọn aa sare lọọ wọ ọ jade, wọn aa bẹrẹ si i jaye ọlọba.

Idris lawọn ileeṣẹ yii o tete fura tori awọn banki tawọn ileeṣẹ naa fi n gba owo jade lawọn jagunlabi yii naa n lo lati fi ko owo lọ, akaunti wọn ni First Bank, Sterling Bank ati Polaris Bank ni wọn n lo, igba ti wọn si fi maa fura, awọn onijibiti ẹda yii ti ṣe wọn ni ṣuta gidi.

Wọn lẹṣẹ tawọn ọdaran yii da ta ko isọri okoolenirinwo o din mẹsan-an (411) ati okoolelọọọdunrun o le mẹjọ (328) iwe ofin iwa ọdaran ipinlẹ Eko.

Ṣe bẹlẹjọ ba ti mọ ẹjọ ẹ lẹbi, ki i pẹ lori ikunlẹ, ọwọ kan lawọn ọdaran yii ti jẹwọ pe loootọ lawọn jẹbi, awọn si ṣetan lati da gbogbo dukia tawọn fowo olowo ko jọ naa pada, pe kile-ẹjọ ṣiju aanu wo awọn, wọn tọwọ bọwe, wọn si yọnda awọn dukia naa.

Adajọ Oluwatoyin Taiwo lo ṣedajọ wọn, o ni kawọn mejeeji lọọ fi ẹwọn ọdun mẹta jura pẹlu iṣẹ aṣekara, ko si saaye fun owo itanran mọ, ki awọn to ku nidii gbaju-ẹ ṣiṣe le fi tiwọn kọgbọn.

Leave a Reply