Monisọla Saka
Gambari pa Fulani ko lẹjọ ninu ni ọrọ ikọlu to waye laarin awọn ikọ apanilẹkunjaye meji kan, ISWAP ati ikọ Boko Haram. Ọpọlọpọ awọn ọmọ ikọ mujẹmujẹ Boko Haram, to fi mọ awọn iyawo ati gbogbo ọmọ wọn to wa ninu igbo Sambisa, to wa ni apa Ariwa Ila Oorun ijọba ibilẹ Bama, nipinlẹ Borno, ti iṣẹlẹ naa ti waye ni wọn dẹni akọlẹbo. Awọn ikọ agbesunmọmi ISWAP ni wọn ni wọn lọọ ya bo wọn nibuba wọn l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ karun-un, oṣu Keje, ọdun 2023 yii.
Gẹgẹ bi iwe iroyin Vanguard ṣe sọ, awọn ikọ ISWAP ni wọn ṣeto lati ru awọn ikọ Boko Haram jade ni ibuba wọn to wa lagbegbe kan ti wọn n pe ni Bula Alhaji Garwaye. Gbogbo awọn ti wọn ka mọbẹ ni wọn si ri i pe awọn pa.
Alaye tawọn ti wọn mọ nipa ọrọ naa ṣe ni pe ojiji lawọn ikọ ISWAP ja wọ ibuba awọn Boko Haram to wa ni Bula Alhaji Garwaye, pẹlu ọkada, gbogbo ẹni ti wọn ri nibẹ pata ni wọn si yinbọn pa.
“Gbogbo awọn obinrin wọn, to fi mọ awọn ọmọ wẹwẹ ti wọn ri nibẹ ni wọn pa, koda wọn o da awọn to jẹ ọmọ ọwọ si. Oku to wa nilẹ nibẹ yoo maa lọ bii aadọta, niṣe ni oku si kunlẹ kaakiri kitikiti.
‘‘Diẹ ninu awọn ọmọ ogun Boko Haram yii ni wọn ribi sa lọ, ṣugbọn awọn ti wọn waa ka wọn mọle palẹ gbogbo awọn nnkan-ini wọn bii ọkada, kẹkẹ ati ibọn mọ. Lẹyin ti wọn ṣe gbogbo eleyii tan ni wọn dana si ibuba ati ami idamọ awọn Boko Haram, wọn si ri i daju pe o jona gburugburu ki wọn too lọ”.
Wọn ni igba akọkọ kọ niyi, tiru ikọlu bayii yoo waye, nitori awọn ikọ Boko Haram paapaa ti ṣe iru nnkan bayii ri fawọn ikọ mi-in lasiko ti wọn fẹẹ gbẹsan awọn eeyan wọn to ku, ati Malam Aboubakar, ti i ṣe adari wọn tẹlẹ, nibẹ ni wọn ti ni ko din ni eeyan bii mẹtalelọgbọn ti wọn pa danu nibi ikọlu ti wọn ṣe lọjọ kejilelogun, oṣu Kejila, ọdun to kọja.