Faith Adebọla, Eko
Bo tilẹ jẹ pe ko jọ pe eebu tawọn eeyan n fi ṣọwọ si gbajugbaja oṣere tiata ilẹ wa nni, Yọmi Fabiyi, dun un wọra, sibẹ, titi dasiko yii ni wọn ṣi n fi ọkan-o-jọkan eebu, epe ati ẹsun ranṣẹ si i lori atẹ ayelujara, wọn lọkunrin naa ti kọyin sibi taye kọju si.
Ọrọ kan ti Yọmi tun ṣẹṣẹ gbe sori ikanni Instagiraamu rẹ lo mu kawọn eeyan maa bẹnu atẹ lu u, wọn niṣe lo n huwa bii ẹni ti nnkan n da laamu, wọn nibi taye kọju si loun kẹyin si.
Lori iṣẹlẹ ti ọrẹ rẹ Ọlanrewaju James Omiyinka (Baba Ijẹṣa) ti wọn fẹsun ifipa ba ọmọde lo pọ kan, tijọba Eko si ti ṣetan lati wọ dele-ẹjọ ni Yọmi tori ẹ kọ ọ sori ikanni rẹ pe: Bi awọn ajafẹtọọ, amofin, awọn eleto ajọṣe, awọn aṣoju ijọba, ọlọpaa, ẹgbẹ awọn lọọya, ati agbalagba onilaakaye ba le ri ẹṣẹ ti Baba Ijẹṣa, ṣugbọn ti wọn ko ri awọn ẹṣẹ to ju meje lọ tawọn agbalagba ti wọn foju han ninu kamẹra aṣofofo CCTV yẹn hu lodi si ọmọde ati ofin Naijiria, a jẹ pe ajalu nla, ojooro, aifararọ ti de ba eto idajọ ododo nilẹ wa niyẹn.”
Yọmi tun kọ ọ sibẹ pe oun ti fiwe ẹsun ṣọwọ si gomina ipinlẹ Eko, ati ile aṣofin Eko, bẹẹ loun si maa fi ẹda iwe naa ṣọwọ si ajọ ajafẹẹtọọ ọmọniyan agbaye ati awọn aṣoju orileede gbogbo, ki wọn le mọ ohun to n ṣẹlẹ si ẹtọ ọmọniyan nilẹ yii, ki wọn si le ṣiṣẹ lori jija fẹtọọ ọmọde de ẹkunrẹrẹ.
O ni yatọ siwa aitọ ti Baba Ijẹṣa hu, awọn agbalagba ti wọn wa nibẹ jẹbi ẹsun iwa aikaramaasiki, ifiyajẹni lọna aitọ, fifi ọmọde dẹ pampẹ ibalopọ, titiiyan mọle lọna aitọ, fifẹtan mu’ni, fifooro ẹmi ẹni lati jẹwọ lọran-anyan, fifiya jẹ ni niṣoju ọmọde, idunkooko mọ ẹmi ẹni, nini nnkan ija oloro lọwọ lai gba aṣẹ, fifi ootọ pamọ fawọn agbofinro, gbigba ọmọọlọmọ ṣọmọ lai bofin mu atawọn ẹsun mi-in.
Yọmi ni ẹṣẹ ti baba ijẹṣa da lawọn eeyan n pariwo, ko si yẹ ki wọn diju si iwa aida sọmọde tawọn agbalagba tọrọ kan hu nibi iṣẹlẹ ọhun.
Bi Yọmi ṣe n ju ọrọ yii sori atẹgun lawọn eeyan ti n fesi. Mister_Yemmy fesi pe “njẹ o mọ pe wọn le fi pampẹ ofin mu ọ pẹlu awọn ọrọ ti o n kọ yii pe o n halẹ mọ awọn tọrọ kan? Ati pe ewo ni tiẹ ninu ọrọ yii gan-an? Ṣe ki i ṣe pe iwọ ati Baba Ijẹṣa jọ n ṣe palapala labẹnu ṣa?”
Ẹlomi-in fesi pe “Wo o, yee sọrọ ti o ta leti, ọrọ ẹ n run leti”, bẹẹ lẹnikan bu Yọmi, o ni “Ṣe ki i ṣe pe bọbọ yii ti fori gbalẹ ṣa. Ara n fu mi si i o”.
Ṣugbọn ẹnikan fesi to yatọ, o ni: “Emi naa ti wo fidio yẹn, gbogbo awọn tọrọ kan pata ni wọn ko o ku, wọn fọkọọpu (fucked up) gidi, paapaa fun bo ṣe jẹ pe ọmọ ti wọn lawọn n ja fẹtọọ ẹ naa ni wọn tun mọ-ọn-mọ sọ sinu ewu ifipa ba ni lo pọ tori wọn fẹẹ dẹ pampẹ fẹnikan. Kinni naa ko boju mu rara, ọmọbinrin naa ati iya rẹ o ṣe daadaa.