Tori burẹdi ati omi ti Samson ji, adajọ sọ ọ sẹwọn ọdun mẹta

Faith Adebọla

Ẹwọn ọdun mẹta gbako ni gende ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn kan, Victor Samson, yoo fi jura, latari bile-ẹjọ ṣe ṣedajọ rẹ, ti wọn lo jẹbi jiji burẹdi atawọn nnkan mi-in, ati pe iwa ole jija ti mọ ọn lara. Wọn ni ko lọọ faṣọ pempe roko ọba ko le kẹkọọ beeyan ṣe n moju kuro ninu nnkan oni-nnkan.

Ipinlẹ Ọṣun niṣẹlẹ yii ti waye lopin ọsẹ to kọja yii. Agbefọba Gbenga Martins, to ṣalaye bọrọ naa ṣe jẹ ni kootu Majisireeti ipinlẹ Ọṣun ti wọn wọ ọdaran naa lọ sọ pe iwa afọwọra ati ojukokoro ti mọ Victor lara, alabọrun si ti fẹẹ dẹwu fun un, tori eyi kọ ni igba akọkọ tọwọ awọn agbofinro n tẹ ẹ, wọn o si tori nnkan meji mu un ri, ole jija yii naa ni.

O ni igba kan wa to lọọ fọ awọn ṣọọbu kan ni ikorita Major Sawmill, to wa niluu Ọrẹ, lọna to lọ siluu Ondo.

Lara nnkan ti jagunlabi ji ni burẹdi aadọta, awọn ọti ẹlẹridodo loriṣiiriṣii, ati omi inu ike.

Wọn lo tun ji paali waini, atawọn nnkan mi-in to joju ni gbese ninu awọn ṣọọbu naa. Oke aja ni wọn lo gba, bo ṣe n fo lati ṣọọbu kan si omi-in lo n jale kilẹ too mọ.

Wọn beere lọwọ Victor boya o ni awijare, ṣugbọn pako lo n wolẹ bii aṣẹwo tilẹ mọ ba.

Adajọ O. A. Ọmọfọlarin, tile-ẹjọ Majisireeti naa gbe idajọ rẹ kalẹ, o lo yẹ ki Victor lọọ kọgbọn gidi wa lati ọgba ẹwọn, iru rẹ ko si yẹ lẹni to gbọdọ maa yan fa-n-da lawujọ, lo ba ju u sẹwọn ọdun mẹta pẹlu iṣẹ aṣekara, ki eyi le kọ awọn mi-in lọgbọn pe ole ki i ṣe nnkan ire.

Leave a Reply