Tori ọrọ Fasiti Ileṣa, APC sọko ọrọ si Adeleke

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress nipinlẹ Ọṣun ti ṣapejuwe bi Gomina Adeleke ṣe fọwọ osi juwe ile fun awọn igbimọ alakooso Fasiti Ileṣa ti gomina ana, Adegboyega Oyetọla, yan, gẹgẹ bii igbesẹ ti ko boju mu rara.

Ọjọ Tọsidee, ọjọ kẹtala, oṣu Kẹrin, ọdun yii ni Agbẹnusọ fun Gomina Adeleke, Mallam Rasheed Ọlawale, fi sita pe gomina ti yan Ọjọgbọn Taiwo Asaolu gẹgẹ bii Ọga-agba akọkọ fun fasiti naa, nigba ti Ọgbẹni Funṣọ Ojo yoo jẹ akọwe (Registrar).

Dokita Mukaila Oyekanmi ni yoo jẹ akapo (bursar) nigba ti wọn kede Ọgbẹni Adewale Ogundipẹ gẹgẹ bii alamoojuto iwe ati akọsilẹ (liberian).

A oo ranti pe ọdun 2022, ki ijọba Alhaji Adegboyega Oyetọla too kogba sile, ni ajọ Nigerian University Commission, NUC, ti fọwọ si i pe ki ile ẹkọ olukọni agba ilu Ileṣa di fasiti, gomina igba naa si ti yan awọn ọmọ igbimọ alakooso ati awọn ọmọ igbimọ alaṣẹ (Principal officers ati Governing Council) fun wọn.

Ṣugbọn nigba ti Gomina Adeleke de, o kede pe ki gbogbo nnkan dawọ duro na lori idasilẹ fasiti naa, nitori o ni awọn nnkan kan tijọba fẹẹ yanju ko too di pe wọn yoo bẹrẹ.

Latigba naa si lawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu mejeeji, APC ati PDP, ti n tahun siraa wọn lori ọrọ fasiti ọhun, ko to di pe ijọba gbe ikede tuntun jade.

Nigba to n fesi lori igbesẹ Adeleke, Adele alaga ẹgbẹ APC nipinlẹ Ọṣun, Sooko Tajudeen Lawal, ni bi gomina ṣe paarọ awọn alakooso fasiti naa ti Oyetọla ti yan tẹlẹ jẹ iwa aini-imọlara ohun to n lọ ati iwa ẹtanu to wa lati da gbogbo eto ijọba ana nu, latari pe wọn ko si ninu ẹgbẹ oṣelu kannaa.

O ni ofin to ṣagbekalẹ fasiti naa ko fun ijọba ipinlẹ lagbara lati yọ ọga agba ati awọn alakooso rẹ nigba to ba wu wọn lai ṣe pe awọn igbimọ alaṣẹ jokoo lati tẹle igbesẹ to yẹ.

Lawal sọ siwaju pe “Yiyan awọn alakoso tuntun fun Fasiti Ileṣa jẹ eyi ti ko bofin mu, ko si le e duro ti wọn ba fi ina ofin yẹ ẹ wo. Igbesẹ Adeleke yii jẹ eyi to buru ninu akọsilẹ itan ipinlẹ Ọṣun, itan ti ko dara nijọba yii si n kọ silẹ fun araa rẹ”

Ṣugbọn nigba to n fesi si ọrọ ọhun, Ọlawale Rasheed ṣalaye pe yiyan awọn alakooso tuntun jẹ ọkan lara awọn ileri Gomina Adeleke lati ri i daju pe fasiti naa jẹ apewaawo kaakiri.

O ni gbogbo awọn ọmọ-bibi ilẹ Ijeṣa ni wọn n gbe sadankata fun Adeleke lori awọn eeyan to ṣẹṣẹ yan ọhun. O ni ko si ọrọ oṣelu nibẹ, gbogbo ilana alakalẹ ni ijọba si tẹle ki wọn too kede orukọ awọn eeyan naa.

Ọlawale gboriyin fun gbogbo awọn ọmọ-bibi ilẹ Ijeṣa fun aduroti wọn pẹlu ijọba Adeleke lori gbogbo igbesẹ ti wọn ti gbe nipa fasiti naa, o si tun rọ wọn lati fọwọsowọpọ pẹlu ọga agba tuntun ki fasiti naa le dagbasoke kiakia.

Leave a Reply