Faith Adebọla, Ogun
Yooba bọ, wọn ni ọrọ to ba jẹ ogun lọ lalọ, ọgbọn ni i jẹ bọ nigbẹyin, oriṣiiriṣii esi-ọrọ, itahun-sira-ẹni ati ọrọ abuku lo ti n waye latari ọrọ ti oludije funpo aarẹ lẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, sọ niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun, pe iwa ọtẹ, ati igbero lati doju eto idibo to n lọna yii ru lo wa nidii owo ilẹ wa tijọba ṣe paarọ awọ rẹ lọwọlọwọ, ati bi ọwọngogo epo bẹntiroolu ṣe n fina mọ awọn ọmọ Naijiria lasiko yii, to si leri p’awọn maa dibo, awọn maa wọle, awọn si maa gbajọba yii lọwọ wọn, bi ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP), ti Tinubu pe ni ẹgbẹ Alaburada leralera ninu ọrọ ẹ ṣe n fesi, bẹẹ ni oludije funpo aarẹ wọn n fọrọ to yọruku lala ranṣẹ si Tinubu ati APC rẹ.
Ẹ oo ranti pe titi dasiko yii ni ọrọ, fọto ati fidio bi Tinubu ṣe sọrọ ọhun lasiko ipolongo ibo sipo aarẹ rẹ, eyi to waye ni papa iṣere Moshood Abiọla Stadium, to wa ni Kutọ, niluu Abẹokuta, lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kin-in-ni yii, ṣi n ja ranyin lori ẹrọ ayelujara, nibi to ti sọ pe:
“Ẹẹ ba parọ inki ara Naira, ibi tẹ ẹ ba gboju si, ọna ko ni i gba’bẹ. Awa la maa wọle.”
O tun ni, “ẹ gbe’po pamọ, ẹ ko Naira pamọ, a maa dibo, a maa wọle, a maa dibo, a maa wọle. City boy, o ti de ba yin, mi o ki i ṣe alejo, ọmọ ile ni mi, mi ti de, oju o ni i ti yin, a maa gbajọba yii lọwọ wọn, awọn ọlọtẹ.”
Ọrọ yii ni oludije funpo aarẹ lẹgbẹ oṣelu PDP, Alaaji Atiku Abubakar, fesi si ninu atẹjade kan to fi lede nipasẹ Oluranlọwọ pataki lori eto iroyin rẹ, Phrank Shuaibu, o ni: “O foju han pe, nitori ko ṣee ṣe fun (Tinubu) lati da eto mimu adinku ba kiko beba Naira kiri tawọn eleebo n pe ni Cashless Policy, ati pipaarọ awọ owo Naira si tuntun, eyi ti banki apapọ ilẹ wa, (CBN) gun le, duro, eyi to daju pe yoo gbegi dina fawọn oloṣelu alowolodu bii iyere ti wọn gbọkan le rira ibo, ti yoo si mu ki eto idibo to maa waye loṣu ta a fẹẹ mu yii tubọ peye, Oludije funpo aarẹ lẹgbẹ oṣelu APC, Bọla Tinubu, ti bẹrẹ si i sunkun lori ifidirẹmi rẹ to n rọ dẹdẹ.
“Ninu ọrọ to sọ l’Abẹokuta, ipinlẹ Ogun, o ni tori oun ni gbogbo eto atunṣe Naira naa ṣe waye. Amọ, Bibeli Mimọ sọ pe “awọn ẹni buruku n sare nigba tẹnikan o le wọn, ṣugbọn olododo yoo laya bii kiniun”.
“Bo tilẹ jẹ pe gbogbo ẹgbẹ oṣelu mejidinlogun to wa nilẹ wa lọrọ atunto Naira naa kan, Tinubu nikan lo figbe ta nipa ẹ, ati nitori Aarẹ Muhammadu Buhari ko lọ sawọn ibi eto ipolongo ibo rakuraku rẹ, o tun sọko ọrọ si Aarẹ, to tun jẹ minisita fun epo rọbi nilẹ wa.
“O yaayan lẹnu, o si paayan lẹrin-in pe isinyii ni Tinubu ṣẹṣẹ mọ p’oun yoo sọrọ lori wahala ọwọngogo epo bẹntiroolu to ti n ba awọn ọmọ Naijiria finra latinu oṣu Keji, ọdun to kọja. L’Ekoo ti Tinubu fi ṣebugbe, latinu oṣu Kọkanla lawọn eeyan ti n to fepo lojoojumọ pẹlu inira. Bawo lo ṣe fẹẹ waa yọ ara ẹ kuro, bawo lo ṣe fẹẹ wẹ ara ẹ mọ ninu ipọnju ati idaamu ti ẹgbẹ oṣelu rẹ ko ba awọn ọmọ Naijiria ni ibo ku ọgbọnjọ yii o?
Tori o ti ri i pe ko si abuja lọrun ọpẹ foun lasiko idibo to n bọ, awawi lo mu bọnu lati sọ pe epo ati Naira lo jẹ koun fidi rẹmi, bẹẹ itiju to n duro de e lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keji to n bọ yii, ko roogun ẹ ṣe o. Aabọ ọrọ la a sọ fọmọluabi.” Gẹgẹ bi Atiku ṣe wi.
Ni ti ẹgbẹ oṣelu PDP, atẹjade kan ti Akọwe ẹgbẹ naa, Kọla Ologbondiyan buwọ lu lorukọ ẹgbẹ wọn ni wọn fi fesi, wọn lo ṣeeyan laaanu pe Tinubu le bẹrẹ si i wa ọna lati ya ara ẹ sọtọ kuro ninu iṣejọba radarada ati ipọnju ti ẹgbẹ oṣelu APC rẹ mu bawọn ọmọ Naijiria, wọn lẹkun eke leyi to n sun l’Abẹokuta yẹn o, tori atọrọ epo to di imi ọkẹrẹ, ati ọrọ Naira tuntun to n pariwo ẹ, ijọba APC rẹ kan naa to fẹẹ ṣe aarẹ labẹ asia rẹ lo ni awọn eto ọhun.
PDP ni “ka sọrọ sibi tọrọ wa, awọn oloṣelu ti ọkọ agboworin n paara ile wọn, ti wọn mọ beeyan ṣe n fowo ra ibo nikan lọkan wọn ko ni i lelẹ pẹlu eto atunṣe Naira ti banki apapọ ilẹ wa gun le yii.”