Faith Adebọla, Eko
Ijọba ipinlẹ Eko ti gboṣuba sadankata fun gbajugbaja akọrin taka-sufee ọmọ Yoruba nni, David Adeleke, tawọn eeyan mọ si Davido, latari ipinnu rẹ pe oun maa pin miliọnu lọna igba ataabọ (N250 million) kaakiri awọn ibudo itọju awọn ọmọ alailobii, atawọn ọmọ orukan lorileede yii.
Atẹjade kan lati ọfiisi Igbakeji gomina ipinlẹ Eko, Dokita Ọbafẹmi Hamzat, eyi to fi lede lọjọ Abamẹta, Satide yii, gboriyin fun akọrin naa, wọn ni iwa ọmọluabi ati ẹlẹyinju-aanu ni igbesẹ to pinnu rẹ ọhun, yoo si ṣanfaani gidi fawọn ti nnkan ku diẹ kaato fun lawujọ.
Tẹ o ba gbagbe, aarin ọsẹ yii ni Davido kede pe oun nilo ọgọrun-un miliọnu naira latọdọ awọn ololufẹ oun lati fi ṣayẹyẹ ọjọọbi rẹ to maa waye lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kọkanla.
Afi bii ẹni pe wọn ti n reti ibeere naa tẹlẹ, laarin ọjọ kan, leni tere eji tere, awọn ololufẹ Davido dawo to ju ọgọrun-un miliọnu naira to loun n wa lọ, apapọ owo to si ti ri laarin ọjọ mẹrin ti sun mọ igba miliọnu.
Davido, ninu atẹjade kan lọjọ Ẹti, fẹmi imoore han fun ifẹ tawọn eeyan ni si i, o loun o ni i lo owo naa fun pati ọjọọbi, oun maa fi ran awọn ọmọ orukan lọwọ ni, o paju owo naa de si 250 miliọnu naira, o si yan igbimọ ẹlẹni marun-un kan ti yoo ṣaayan pinpin owo naa kaakiri awọn ibudo itọju ọmọ orukan to wa lorileede yii.