Faith Adebọla
Igbadun iṣẹju diẹ, yunkẹyunkẹ takọ-tabo ẹẹkan ṣoṣo ti ṣakoba fun ọdọmọkunrin kan, Wasiu Ẹniọla Ibrahim, adajọ da a lẹbi pe o ba ọrẹbinrin ẹ laṣepọ pẹlu ipa. Bo tilẹ jẹ pe ọrẹbinrin ti wọn forukọ bo laṣiiri ọhun ki i ṣe ọmọde, sibẹ, wọn ni ibasun ti Wasiu ṣe fun un ki i ṣe pẹlu ifẹ-inu rẹ, wọn lo fọọsi ẹ ṣe e ni, ladajọ ba ni ko lọọ lo iyoku aye rẹ lahaamọ ẹwọn, bo ba tun aye wa, yoo mọ peeyan ki i fipa bobinrin sun.
Adajọ ile-ẹjọ giga kan to n gbọ awọn ẹsun akanṣe to ba jẹ mọ ti ibalopọ ati iwa ọdaran abẹle, Sexual offences and domestic violence court, eyi to fikalẹ siluu Ikẹja, nipinlẹ Eko, Onidaajọ Rahmon Oshodi, lo gbe idajọ naa kalẹ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ogunjọ, oṣu Kẹfa, ọdun yii.
Gẹgẹ bo ṣe wa lakọọlẹ, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹfa, ọdun 2021, ni ọdaran yii huwa palapala ọhun, ti wọn si kọkọ foju rẹ bale-ẹjọ lọjọ kin-in-ni, oṣu Kejila, ọdun 2021 kan naa.
Lara ẹsun ti wọn fi kan Wasiu ni pe o ṣakọlu si ọrẹbinrin ẹ kan, o tun fipa ba a laṣepọ, eyi ti wọn lo ta ko isọri ọtalerugba iwe ofin iwa ọdaran nipinlẹ Eko.
Bo tilẹ jẹ pe titi ti wọn fi fẹẹ gbe idajọ kalẹ ni afurasi naa n sọ pe oun ko jẹbi, adajọ ni ẹri to wa niwaju kootu fihan pe o jẹbi daadaa, ati pe awawi lasan ni gbogbo awijare rẹ.
Gẹgẹ bi ọmọbinrin ti ọrọ ọhun ṣẹlẹ si ṣe sọ lasiko igbẹjọ, o ni loootọ ni Wasiu dẹnu ifẹ kọ oun, toun si sọ fun un pe oun aa maa ro o.
O ni lọjọ to maa huwa buruku naa, niṣe lo ni ki oun waa ki oun nile, oun si lọ, ọsan loun lọọ ba a ninu ile oniyara meji, ruumu ati palọ to n gbe, oun si jokoo si yara akọkọ, iyẹn palọ. O ni b’oun ṣe debẹ loun ti sọ fun un pe oun ko ni i pẹẹ pada o, tori oun ko fi bẹẹ raaye.
“Nigba to ya lo jooko sẹgbẹẹ mi, o loun laiki irun ori mi, mo lo ṣeun, o lọmọ ibo ni mi, ati pe njẹ mo mọ ipo ti ẹjẹ mi wa, iyẹn genotype mi, mo ni mi o mọ ọn, lo ba ni bawo ni ma a ṣe dagba to bayii ti mi o ni i mọ genotype mi. O ni kin ni mo fẹẹ jẹ ki ni mo fẹẹ mu, mo si ni ko ma ṣeyọnu, mo ti wa pa.
“Lẹyin naa lo bẹrẹ si i fọwọ pa mi lara, o n romaansi mi, o fọwọ tẹ mi lọmu, mo ni eyi to ṣe yẹn naa ti to, mo fẹẹ maa lọ, afi bo ṣe dide fuya, to lọọ yii kọkọrọ si ilẹkun, ki n too mọ ohun to n ṣẹlẹ, o ti gbe mi tan nilẹ, o gbe mi wọnu yara, lori bẹẹdi ẹ. Mo bẹrẹ si i pariwo, mo n lọgun boya ẹru yoo ba a lati fi mi silẹ, nibi ti mo ti n ṣagbaja pẹlu ẹ ni gilaasi kan ti fọ, niṣe lo yọ ada si mi, to ni ti mi o ba dakẹ, oun maa pa mi. Eyi lo jẹ ki n dakẹ, lo ba bọ ṣokoto ti mo wọ tipatipa, o si ba mi laṣepọ lọran-an-yan.
“Lanlọọdu ẹ to gbọ ariwo ti mo pa pe e lori aago, nigba ti mo si fẹẹ maa lọ, awọn ọrẹ ẹ kan bayii waa ba mi, wọn bẹrẹ si i bẹ mi pe ki n fori jin in, wọn ni oro ifẹ lo mu un.”
Amọ olujẹjọ naa ni ni tododo, oun fọwọ pa ọmọbinrin yii lara, oun romansi ẹ, amọ oun o fipa ba a laṣepọ rara, niṣe lo gba foun. O ni o ba awọn dukia oun kan jẹ nibi to ti n jasẹ wai-wai, lo ti fẹsẹ fọ gilaasi.
Adajọ ni eke ni olujẹjọ yii, tori ko sẹni to maa ba aja lẹnu isa to gbọdọ tun beere pe ki laja naa le debẹ. O ni ẹlẹrii mẹrin ọtọọtọ ni olupẹjọ ko kalẹ, pẹlu awọn ẹri mi-in to fihan pe ọrọ ibalopọ waye lọjọ naa, ati pe ibalopọ ọhun ki i ṣe lọwọ ẹrọ wọọrọwọ, o ni tipa-tikuuku ninu.
Adajọ tun ni agbẹjọro olujẹjọ ti rawọ ẹbẹ soun pe kile-ẹjọ wo onibaara oun ṣe laaanu, ki wọn din ijiya ẹṣẹ rẹ ku, leyii to fihan pe o ti gba loootọ pe oun tọ si ijiya daadaa.
Tori ẹ, ile-ẹjọ yii yoo ṣaanu rẹ, amọ iwa to hu yii, awọn eeyan bii ẹranko lasan ekeji aja ni wọn maa n ṣeru ẹ, iru wọn o tun gbọdọ maa yan laarin awọn ọmọluabi, wọn ni ko kọja si keremọnje, ibẹ si ni ko wa titi tọlọjọ yoo fi de ba a, n ladajọ ba pa iwe idajọ rẹ de.