Toyin Abraham mu iya ọkọ ẹ lọ si Canada

Gbogbo awọn to ri fọto arẹwa oṣere ilẹ wa nni, Toyin Abraham, ti awọn eeyan tun fẹran lati maa pe ni Iya Ire, ni wọn n ṣadura fun un, wọn ni yoo pẹ nile Kọla kanrin kese, oun naa yoo si jẹun ọmọ. Wọn ni aya to daa teeyan fi n tọrọ iyawo fẹ ni. Eyi ko sẹyin ajọṣepọ to dan mọran to wa laarin oṣere yii ati iya to bi ọkọ rẹ, Kọla Ayeyẹmi.

Laipẹ yii ni fidio kan gba ori ẹrọ ayelujara, nibi ti Toyin, ọkọ, rẹ ọmo wọn ọkunrin, Ire ati ẹgbọn rẹ, Temitọpẹ ti rin irinajo lọ si orileede Canada.

Eyi to ya gbogbo eeyan lẹnu ju ni ti mama ọkọ Toyin to tẹlẹ wọn lọ si irinajo yii.

Ninu fidio naa ni awọn oṣere to jẹ tọkọ-tiyawo yii atawọn ọmọ wọn pẹlu mama agba ti balẹ sorileede Canada, ti awọn ololufẹ wọn kan si waa pade wọn lọna, ti wọn yẹ wọn si, ti wọn si ṣe apọnle wọn daadaa.

Mama Kọla, bi gbogbo eeyan ṣe maa n pe iya naa ko le pa idunnu rẹ mọra, ayọ han loju iya yii ninu fọto kan to ya ni kete ti wọn wọn Ontario, ni Canada.

Fọtọ ọhun ni ọmo rẹ, Kọla, gbe sori ayeluara, to si kọ o sibẹ pe ‘‘Eleyii jẹ lara ilakaka mi(Iya mi). O yẹ ki ẹ maa nifẹẹ awọn obinrin to wa ninu aye yin’’.

Bi Kọla ṣe gbe fọto naa sita ni awọn eeyan ti n ki i, ti wọn si n ṣadura fun mama naa pe yoo jẹun ọmọ pẹ titi.

Bi wọn ṣe n ki Kọla naa lawọn ololufẹ wọn n gbadura fun Toyin, wọn ni obinrin daadaa lọọdẹ ọkọ ni. Wọn ni gbogbo eleyii ṣee ṣe nitori ifẹ to wa laarin oṣere naa ati iya ọkọ rẹ ni. Wọn ni ọpọ awọn obinrin iwoyi ni ki i fẹẹ ri imi iya ọkọ wọn laatan, ti wọn maa n sọ pe awọn ko fẹẹ ri iya ọkọ awọn, ṣugbọn ti Toyin ko ri bẹẹ.

Aimọye igba ni oṣere yii ti gbe fidio ibi ti oun pẹlu iya ọkọ rẹ ti n ṣere, ti wọn n ṣawada lọlọkan-o-jọkan sori ẹrọ ayelujara.

Bakan naa ni ko fi ọrọ ọmọ ti ọkọ rẹ ti bi fun obinrin mi-in ko too fẹ ẹ, iyẹn Temitọpẹ, ṣere rara, bii ọmọ lo ṣe mu un, itọju to si le fun ọmọ to bi ninu ara rẹ lo n fun ọmọ yii. Gbogbo igba lawọn eeyan maa n ṣadura fun un ti wọn ba ti ri oun atọmọ naa.

Eyi mu ki awọn ololufẹ rẹ tubọ nifẹẹ rẹ si i, ti wọn si n gbadura fun un pe eṣu ko ni i le e nidii ẹru rẹ.

Lọwọlọwọ ba a ṣe n sọ yii, bẹ ẹ ba wa Toyin ati ọkọ rẹ dele ti ẹ ko ba wọn, orileede Canada ni wọn ti lọọ fara nisinmi pẹlu awọn ọmọ wọn ati iya ọkọ rẹ.

Leave a Reply