Toyin gba iku oniku ku, awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun to fẹẹ pa ọrẹkunrin rẹ ko ri i ni wọn fi ṣa ọmọbinrin naa pa  

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Yoruba ni ole ko ni i ja agba ko maa ṣe e loju firi. Owe yii lodifa fun owuyẹ kan to sọ pe awọn afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun lo ṣeku pa akẹkọọ gbogbonise tijọba apapọ to wa niluu Ọffa, nipinlẹ Kwara, (Federal Polytechnic, Ọffa). Omidan Toyin Bamidele, to wa ni HND1, lẹka ti wọn ti n kọ nipa imọ nipa ounjẹ (Food Technology), ni awọn ika eeyan kan ka mọ’nu ile ẹ, ti wọn si ṣa a pa sibẹ.

Ọkan lara awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ, ṣugbọn to ni ka ma darukọ oun sọ fun ALAROYE pe ni nnkan bii aago mẹfa irọlẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kọkanla yii, lawọn afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun ọhun ya bo agbegbe Dapson, nibi ti Toyin n gbe niluu Ọffa, pẹlu ada, aake atawọn ohun ija oloro lọkan-o-jọkan, ti gbogbo awọn eeyan to ri wọn si n sa asala fun ẹmi wọn pẹlu awọn ohun ija oloro ti wọn ko dani ọhun.

ALAROYE gbọ pe yara Toyin ni wọn gba lọ taara, bi wọn ṣe foju kan an ni wọn bẹrẹ si ṣa a laaake ati ada bii  ẹran Ileya, nigba ti ẹmi bọ lara rẹ tan ni wọn too fi i silẹ ninu agbara ẹjẹ, ti wọn si sa lọ.

O ni wọn lo to iṣẹju mẹẹẹdogun ki wọn too kuro ninu yara Toyin, nigba ti awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ọhun lọ tan lawọn too wọ yara arẹwa obinrin yii, tawọn si ba a ninu agbara ẹjẹ, ti wọn si ti kun un bii ẹran.

Ẹni yii ni eyi lo mu kawọn lọọ fi iṣẹlẹ naa to awọn alaṣẹ ileewe naa leti ki wọn le gbe igbeṣẹ to tọ.

O tẹsiwaju pe Toyin jẹ ọrẹbinrin ọkan lara olori ọmọ ẹgbẹ okunkun igun kan, ṣugbọn nigba ti wọn fẹẹ pa iyẹn to sa lọ ni wọn fi lọọ pa ọrẹbinrin rẹ, Toyin Bamidele.

Wọn ni o ti wa ninu aṣa ati iṣe awọn akẹkọọ Ọffa Poli, ki wọn maa para wọn lasiko ti wọn ba n ṣe ayẹyẹ ikẹkọọ-jade, ati pe lọjọ Aje, Mọnde, ọṣẹ to kọja yii, ni wọn ṣe ayẹyẹ naa, ti wọn si pa akẹkọọ kan toun naa jẹ ọkan lara awon ọmọ ẹgbẹ okunkun ọhun siwaju geeti ileewe yii. Awọn ọlọpaa lo pada lọọ palẹmọ oku ọhun.

Awọn alaṣẹ ileewe naa ti fofin de ayẹyẹ ikẹkọọ-jade ti wọn tun maa n lọọ ṣe nita ileewe, ki wọn le raaye pa ẹni ti wọn ba fẹẹ pa ninu wọn, nitori pe lọjọ naa gan-an ni ọjọ iku awọn ti wọn ba fẹẹ pa maa n pe.

Leave a Reply