Aderounmu Kazeem
L’Ọjọruu, Wẹsidee, ni olu ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Eleweran niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun, ṣafihan ọkunrin ẹni afurasi kan, Tunde Bello, ti wọn fẹsun kan pe o ji eeyan gbe, to tun fipa ba obinrin to ji gbe yii lo pọ.
Ọjọ kẹtadinlogun, ọsu kẹsan-an, ọdun to kọja, ni wọn sọ pe iṣẹlẹ ọhun waye ni Mowe, nijọba ibilẹ Ọbafẹmi Owode, nipinlẹ Ogun, ni nnkan bii aago marun-un idaji.
Arabinrin kan ti ileeṣẹ ọlọpaa fi orukọ bo laṣiiri lo wọ mọto Tunde Bello ni Mowe, lakooko to n ji lọ sibi iṣẹ ẹ l’Ekoo.
Mọto Hyundai lo wọ lagbegbe Ogunrun, nigba to si de ojupopo nla ni Mowe lati kọri si ọna Eko ni Tunde yi ori mọto pada si ọna Ibadan, to si gbe obinrin yii lọ sinu igbo kan nibẹ.
Nibẹ naa ni wọn sọ pe o ti lu arabinrin ọhun ni ilukulu, to si tun fipa ba a lopọ.
Wọn ni lẹyin to ṣe bẹẹ tan lo tun fipa mu un ko maa pe awọn mọlẹbi ẹ lati fowo ranṣẹ sinu akaunti ẹ nibẹ, ti ko ba fẹẹ fiku ṣefa jẹ.
Owo to to ẹgbẹrun lọna ogoje naira (#140,000) ni Tunde to n fi mọto ayọkẹlẹ gbero laarin Mowe si Eko yii gba lọwọ obinrin ọhun lẹyin to ti fipa ba a lopọ gẹge bi awọn ọlọpaa ṣe sọ.
Ni kete ti obinrin yii bọ lo ti fọrọ ọhun to ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Mọwe leti, nibẹ lawọn yẹn ti bẹrẹ iwadii tiwọn.
Ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kin-in-ni, ọdun yii, lọwọ tẹ ẹ, bẹẹ ni wọn lo ti jẹwọ, ti ileeṣẹ ọlọpaa si ti sọ pe yoo foju bale-ẹjọ laipẹ yii.
ALAROYE lanfaani lati fọrọ wa Tunde Bello lẹnu wọ, alaye to ṣe ni pe loootọ loun gbe obinrin naa ni mọto, ti oun ṣe bii ẹni to n gbero lọ si igboro Eko.
Tunde ni, “Sadeede ni ẹmi buruku yii ba le mi, mi o ni in lọkan lati ja a lole rara, niṣe ni mo gbe mọto yẹn dori kọ ọna Ibadan, dipo Eko, ti mo ni mo n lọ. Nibi to ti fẹẹ fariwo bọnu ni mo ti da igbaju nla bo o, bi mo ṣe fi bẹliiti to yẹ ko fi kọrun so o mọ ara siiti ọkọ niyẹn, ti mo si gbe e wọnu igbo kan lọ. Loju-ẹsẹ nibẹ ni mo ti sọ pe owo ọwọ ẹ ni mo fẹẹ gba, nigba ti mo si wo baagi ẹ, ẹgbẹrun mejidinlogun naira pere lo wa nibẹ. Nibi ti mo ti ni ko maa pe awọn eeyan ẹ niyẹn. Eeyan meji lo fi ẹgbẹrun lọna aadọta naira (N50,000) ranṣẹ, owo bii ẹgbẹrun lọna ọgọrun un ni mo ri gba, ki n too tu u silẹ.”
Tunde fi kun un pe oun ko fipa ba obinrin naa sun gẹge bi awọn ọlọpaa ṣẹ sọ, bo tilẹ jẹ pe ọlọpaa kan sọ nibe pe oun nilo fọnran ti oun ka ọrọ ẹ si nibi to ti n ka boroboro pe loootọ loun ba obinrin naa lajọṣepọ lẹyin toun gba owo ọwọ ẹ tan.
Ọkunrin yii sọ pe foonu ọmọbinrin naa ti oun gba lọwọ ẹ lo jẹ ki awọn ọlọpaa ri oun mu nigba ti wọn pe oun pe awọn fẹẹ gbe iṣẹ fun oun.
O fi kun un pe iṣe awọn to n kun mọtọ loun n ṣe, o ni oun maa n ri iṣẹ gba daadaa, ati pe tẹtẹ ti oun fi gbogbo owo oun ta lo ko ironu ba oun, ti oun fi kọ lu obinrin naa, ko too di wahala si oun lọrun bayii.