Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, to n bọ, iyẹn ọgbọnjọ, oṣu Karun-un, ọdun yii, nidajọ yoo waye lori ẹjọ ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan Dokita Rahmon Adedoyin to ni ileetura Hilton, niluu Ileefẹ, nipinlẹ Oṣun ṣatawọn oṣiṣẹ rẹ mẹfa.Onidaajọ Bọla Adepele-Ojo lo n gbọ ẹjọ naa lati oṣu Keji, ọdun 2022, ti wọn ti fi ẹsun mejidinlogun kan Adedoyin atawọn oṣiṣẹ rẹ mẹfa pe wọn lọwọ ninu iku to pa akẹkFọ fasiti OAU Ifẹ, Timothy Adegoke, sinu otẹẹli Hilton, loṣu Kọkanla, ọdun 2021.Lasiko igbẹjọ to waye gbẹyin lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ni agbejoro fun olujẹjọ kin-in-ni, iyẹn (Adedoyin), Yusuf Alli SAN, ti sọ fun kootu pe agbẹjọro to n ṣoju ijọba, Fẹmi Falana (SAN), ko ni agbara ati aṣẹ labẹ ofin lati da si orọ ẹjo naa.Alli ṣalaye pe Falana ko gba nnkan ti wọn pe ni ‘Fiat’ lati ṣoju adajọ agba ati kọmiṣanna feto idajọ nipinlẹ Osun lati ṣe ẹjọ naa, nitori idi eyi, ki ile-ẹjọ fagi le gbogbo igbesẹ ati atotonu ti Falana ati ekeji rẹ, Fatimah Adeṣina, ti gbe ninu igbẹjọ naa.Bakan naa ni awọn agbẹjọro to ku; K.K. Ẹlẹja, Roland Otario, Muritala Abdulrasheed sọ pe Falana ko ni aṣẹ labẹ ofin lati ṣoju ijoba ninu igbẹjọ naa.Ṣugbọn Falana sọ fun ile-ẹjọ pe awọn ojugba oun ko ni agbara lati da oun duro, o ni oun ko nilo lati gba aṣẹ, iyẹn Fiat, ki oun too ṣoju ijọba, niwọn igba ti adajọ agba (Attorney General) ko ba ti sọ pe oun kọ loun ran oun niṣẹ.Lẹyin atotonu awọn mejeeji ni Onidaajọ Adepele Ojo sọ pe oun yoo gbe idajọ kalẹ lori ariyanjiyan naa nigba toun ba ḟẹẹ ka idajọ lori ẹsun iwaju oun.Bayii ni awọn agbẹjọro olujẹjọ ṣalaye fun kootu pe awọn fara mọ gbogbo atotonu ati alaye igbẹjọ to wa ni kootu (Adoption of written addresses), gbogbo wọn ni wọn si sọ pe awọn onibaara awọn ko jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan wọn.Yusuf Alli ni tiẹ sọ pe ko si ẹri kankan to fidi rẹ mulẹ pe Adedoyin mọ ohunkohun nipa iku Adegoke, o ni ọna kan ṣoso ti wọn ti mẹnuba orukọ rẹ ni pe oun lo ni ileetura Hilton, ko si si nnkan to buru nibẹ.Awọn agbẹjọro fun awọn olujẹjọ waa bẹ kootu lati tu wọn silẹ, ki alare ma baa ku sipo ẹlẹbi.Ni ti Falana, o ni ko si ẹlẹṣẹ to gbọdọ lọ lai jiya, o ni gbogbo wọn patapata ni wọn jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn.Lẹyin eyi ni Onidaajọ Adepele Ojo dupẹ lọwọ awọn agbẹjọro agba naa fun ifowọsowopọ wọn ni gbogbo asiko ti wọn fi ṣe igbẹjọ ọhun, o si ṣeleri pe oun yoo fi ọjọ idajọ ranṣẹ si gbogbo wọn.Ni bayii, iroyin to tẹ ALAROYE lọwọ, eleyii ti ọkan lara awọn agbejoro olujẹjọ, Fatimah Adeṣina, fidi rẹ mule ti fihan pe ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ to n bọ, ni pin-pin-pin yoo pin lori ẹjọ naa nile-ẹjọ giga ipinlẹ Ọṣun.