“Gbogbo wa o le sun ka kori sibi kan naa, ti gbogbo wa ba ni ka maa duro de ohun tijọba apapọ fẹẹ ṣe, niṣe la maa di ẹru nilẹ wa, iyẹn ta o ba ti i di ẹru ọhun bi mo ṣe n sọrọ yii. Ohun to n ṣẹlẹ lo mu ki Sunday Igboho gbe igbesẹ to gbe, ọrọ naa toju su u ni, o si pinnu lati ṣe nnkan kan nipa ẹ, ọna toun si mọ to le gba ṣe nnkan kan nipa ẹ lo tọ yẹn. Ti aṣiṣe ba wa ninu ohun to ṣe, a le sọ fun un ni, ka ran an lọwọ, ka ba a ṣatunṣe ẹ, ṣugbọn ohun to ṣe pataki ju lọ ni pe akin ọkunrin ni, o si laya lati doju kọ ipo ti ko dara ti gbogbo wa ti n ṣaroye le lori. Iyẹn gan-an ni koko, ki i ṣe aṣiṣe tabi ofin la fẹẹ maa ba ja lori ẹ.”
Ogbontarigi ọmọwe ati ọnkọwe to ti gba ami-ẹyẹ kari aye nni, Ọjọgbọn Wọle Ṣoyinka, lo ṣe bayii sọrọ lọjọ Aiku, Sannde yii, nigba to n fesi fawọn akọroyin lori atẹ ayelujara nipa ero rẹ lori bi ọkunrin ajijagbara ti wọn n pe ni Sunday Igboho ṣe n le awọn Fulani darandaran kuro lawọn ipinlẹ Yoruba laipẹ yii.
O loun ko figba kan sọ pe Sunday wa ninu awọn akọni ilẹ Yoruba gẹgẹ bawọn kan ṣe n sọ, ṣugbọn ero oun nipa igbesẹ Sunday Igboho ni pe o daa bi ọkunrin naa ṣe laya, to si ta gbogbo wa ji.
Ṣoyinka ni ilu yii ti bajẹ kọja sisọ, ọrọ aabo to mẹhẹ lo si buru ju ninu ibajẹ naa. O ni ki i ṣe pe ka kan wa ṣaa, ṣugbọn o yẹ ka wa pẹlu iyi ati ẹyẹ ni. Iyi ati ẹyẹ wa bii eniyan ti sọnu lasiko yii, wọn ti po gbogbo ẹ mẹrẹ, iyẹn lo fi jẹ pe oju yẹpẹrẹ lawọn ọbayejẹ ilẹ yii fi n wo gbogbo eeyan.
Ko too pari ọrọ rẹ, Ṣoyinka ni ọwọ tijọba fi mu ọrọ awọn Fulani darandaran to n paayan, ti wọn n jiiyan gbe, ti wọn si n ṣe oriṣiiriṣii aburu yii, ohun to le da ogun abẹle silẹ ni, ina nla tijọba ko ni i le fẹ pa ni. O ni bi Aarẹ Buhari ṣe dakẹ, ti ko sọrọ lori awọn Fulani darandaran yii, didakẹ naa fihan pe o fara mọ iwa ti wọn n hu ni.
Ṣoyinka ni bawọn Fulani darandaran ṣe n da wahala silẹ lojoojumọ yii le yọri si ogun abẹle fun orilẹ-ede Naijiria. O ni togun abẹle ba ṣẹlẹ, oun atawọn tọrọ ohun to n ṣẹlẹ bayii ti su maa ja fitafita, oun aa si fi awọn nnkan ini oun ja lati gba awọn eeyan silẹ ninu igbekun awọn aninilara.
O ni ta a ba fẹ ki nnkan yii dawọ duro, ko ma buru ju bo ṣe wa yii lọ, afi ki Aarẹ Muhammadu Buhari ba wọn ọmọ orileede yii sọrọ lai fọrọ bọpo bọyọ, ko sọ fawọn darandaran onimaaluu pe ki wọn yee tẹ ẹtọ awọn araalu mọlẹ, ki wọn jawọ ninu fifi okoowo tiwọn fa inira fọmọlakeji wọn.
Baba naa rọ Aarẹ Buhari lari paṣẹ fawọn agbofinro lati daabo bo araalu, aijẹ bẹẹ, oju aarẹ to n gbe sẹyin awọn darandaran ọdaran lawọn eeyan yoo maa fi wo o.
Ọpọ awọn to n ka ọrọ Ṣoyinka lori atẹ rẹ ni wọn ti n kan saara sọkunrin naa fun bo ṣe n sọrọ soke lasiko yii, wọn ni ọrọ rẹ fawọn niṣiiri.