Aderounmu Kazeem
Wahala buruku lo bẹ silẹ lana-an, Ọjọruu, Wẹsidee, laarin awọn onimọto atawọn ẹṣọ ojupopo l’Ekoo (LASTMA), nitori ti wọn wa mọto lojuna BRT.
ALAROYE gbọ pe ojuna Ikorodu ni wahala ọhun ti ṣẹlẹ, nigba ti awọn ẹṣọ LASTMA mu mọto bii mejila ati ọkada.
Pẹlu ibinu ni wọn sọ pe awọn eeyan kan lara awọn ti wọn mu yii fi kọlu mọto tawọn LASTMA fi n wọ mọto lọ sọgba wọn, ti wọn si ba a jẹ.
Ọkan lara awọn ọga agba ileeṣẹ LASTMA to ko awọn ẹṣọ ọhun jade, Ọgbẹni Kayode Odunuga, sọ pe, “Deede aago mesan-an aabọ aarọ la ti jade, mọto ayokẹle to jẹ ti aladaani meje lọwọ tẹ ti wọn n gba ojuna BRT, bẹẹ lọwọ ba mọto akero mẹta ati ọkada mẹrin.
“Lara awọn ta a tun mu ni ọkunrin ṣọja kan. Ọkada loun gun ni tiẹ lojuna BRT, ati pe o fẹẹ waa gba awọn eeyan ti a mu silẹ ni. Ibinu ni wọn fi kọlu mọto ta a gbe wa, a si ti fọrọ ọhun to awọn alaṣẹ leti lati mọ igbesẹ to kan.”