Wahala iyawo mi ti pọ ju ni mo ṣe fẹyawo keji, mi o ṣe mọ- Kazeem

Adewale Adeoye

Iwaju Onidaajọ Abilekọ S.M Akintayọ, tile-ẹjọ kọkọ-kọkọ kan to wa ni Mapo, niluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ, ni awọn tọkọ-taya meji kan, Ọgbẹni Kazeem Jẹjẹ ati Abilekọ Kafilat Jẹjẹ, gbe ara wọn lọ. Kazeem lo gbe ẹjọ iyawo rẹ  lọ sile-ẹjọ ọhun, nnkan to si n fẹ ni ki  adajọ  tu igbeyawo  to wa laarin awọn mejeeji ka, ki kaluku awọn maa lọ layọ ati alaafia bayii.

Ninu ọrọ rẹ ni Kazeem ti sọ pe, ‘‘Oluwa mi, ẹbẹ kan ṣoṣo ti mo bẹ bayii ni pe kẹ ẹ tu igbeyawo ogun ọdun to wa laarin emi pẹlu iyawo mi yii ka, kẹ ẹ si kilọ fun un pe ko gbọdọ waa ba mi lẹnu iṣẹ mi mọ lati waa fa wahala pẹlu mi. Ọrọ rẹ ti su mi patapata, mi o ṣe mọ, ko sifẹẹ laarin awa mejeji mọ, ojoojumọ, ija ni ninu ile. Kẹ ẹ si maa wo o, ni nnkan bii ogun ọdun sẹyin ni mo pade rẹ, gbogbo iwa rẹ lo tẹ mi lọrun pata, a ṣeto idana, bẹẹ ni mo sanwo ori rẹ fawọn ẹbi rẹ. Ko sohun ti wọn beere lọwọ mi ti mi o fun wọn. Ṣugbọn ko pe rara ta a fẹra wa sile tan ti iyawo mi yii bẹrẹ si i yọwọ-kọwọ, wahala ni lọjoojumọ, nigba to tun ya lo ba tun n lọọ rojọ mi nita pe mo ti lo nnkan ọmọkunrin mi lati fi ṣoogun owo loun ko ṣe ri ọmọ bi latigba ta a ti ṣegbeyawo.

‘‘Ko sibi ti mo le de bayii, ṣe lawọn eeyan aa maa fi mi ṣe yẹyẹ, bẹẹ ki i ṣe pe mo lowo lọwọ ka baa sọ pe loootọ ni mo lo nnkan ọmọkunrin mi fun oogun owo. Ọpọ igba ni mo ti lọọ fẹjọ rẹ sun awọn obi rẹ, ṣugbon ko si iyato ninu ọrọ rẹ. Bi mo gbe igba ninu ile, mi o mọ ọn gbe ni, ko sigba ti ma a jade kuro ninu ile, ṣe niyawo mi a maa tu gbogbo ẹru mi lati wo o boya mo loogun kan ti mo fi pamọ fun un. Nigba to ya ni baba iyawo mi gba mi nimọran pe ki n lọọ fẹyawo keji sita. Amọran pataki ọhun ni mo tẹle ti mo fi lọọ fẹyawo miiran sita bayii. Ọlọrun si ti ṣe e, iyawo ọhun ti bimọ fun mi, eyi to fihan gbangba pe irọ niyawo mi n pa mọ mi pe mo ti lo nnkan ọmọkunrin mi lati fi ṣoogun owo. Ẹ ṣaa ba mi le e jade kuro ninu ile mi lohun ti mo n fẹ bayii’’.

Niwọn igba ti ko si olujẹjọ, iyẹn Abilekọ Kafilat Jẹjẹ, nile-ẹjọ, adajọ ile-ẹjọ naa sun igbẹjọ siwaju di ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2024 to n bọ yii.

Bakan naa lo kan an nipa fawọn akọwe kootu pe ki wọn ri i daju pe wọn fun olujẹjọ niwee ipẹjọ, ko le yọju sile-ẹjọ lọjọ ti igbẹjọ rẹ maa tun waye.

Leave a Reply