Wahala lagbo oṣere Yoruba, Yọmi Fabiyi kọju ija si Jaiye Kuti

Monisọla Saka

Gbajumọ oṣere ilẹ wa kan to fẹran lati maa sọ si ọrọ to ba n lọ, agaga lagboole tiata, Yọmi Fabiyi, ti sọ kobakungbe ọrọ si arẹwa oṣerebinrin ẹlẹgbẹ ẹ, Jaiye Kuti. Eyi ko ṣẹyin bi obinrin naa ṣe sọrọ sawọn onitiata ti wọn n tọrọ owo lori ẹrọ ayelujara.

Bọrọ ṣe ri lara Kuti, to si ju u kalẹ ninu fidio to ṣe lo mu ki Yọmi Fabiyi fun un lesi, to si sọko ọrọ si i gidigidi.

O ni iwa igberaga ati arifin nla loun ri ninu ọrọ ti Jaiye sọ, nitori ko sẹni to gbe abọ gaari wa sile onigbeeraga ara ẹ, ati pe to ba mọ pe oun ko ni iranlọwọ kankan lati ṣe fun wọn, ki lo de ti ko fi wọn silẹ pẹlu kadara wọn.

Yọmi ni, “Tẹnikẹni ba nilo iranlọwọ, to si gbe ọrọ ẹ si ojutaye nipasẹ lilo orukọ ileeṣẹ tabi ọja to n ta, orukọ ara ẹ tabi oju ẹ nikan, emi o ro pe iyẹn kan ẹnikankan, tabi ko jẹ inira fẹnikẹni. Ti o ko ba nipa lati ran awọn eeyan yii lọwọ lati pada bọ sipo lori ofo to ṣe wọn latari awọn ti wọn n ta iṣẹ wa lọna aitọ (piracy), tabi awọn ti wọn n gbowo lọ lọwọ ẹni nitori òwò ti wọn jọ n ṣe, iba daa ko o jẹ ki wọn rimu mi. Ti awa oṣere aye ode oni kan tun san ni, ki i ṣe pe awa naa rọwọ mu, tabi pe tiwa naa daa to bẹẹ ju bẹẹ lọ.

“O yẹ ka kọ nipa bi wọn ṣe n fọ̀wọ̀ wọ eeyan lori ipinnu yoowu to ba ṣe, tabi igbesẹ to ba gbe. Pe a n fi nnkan we nnkan yẹn ko nitumọ. Loju temi o, o daa kawọn irawọ oṣere yii maa tọrọ ju ki wọn bẹrẹ si i gbe egboogi oloro, iwa jibiti lilu, oogun owo ṣiṣe atawọn iwa buruku mi-in, lati le la akoko to le yii kọja lọ.

Boya ki wọn si gbe ọrọ owo titọrọ gba ọna mi-in to tun jọju daadaa ni, nitori a ni lati sọ eyi to n jẹ ootọ ọrọ, ọpọlọpọ awọn agba oṣere yẹn ni wọn n jiya, ti wọn n daamu labẹnu, ti wọn ko ba si beere fun iranlọwọ, afaimọ ni ki wọn ma ku rederede.

“Ẹ jẹ ko ye wa pe ko si bi iṣesi tabi igbesẹ eeyan kan ṣe le maa bi ẹ ninu tabi ni ẹ lara to, ti ko ba ti ta ko ofin orilẹ-ede yii, ti ki i si i ṣe ohun teeyan ko gbọdọ ṣe, iwa igberaga, ọdaran ati ailarojinlẹ ni lati maa sọrọ buruku siru eeyan bẹẹ”.

Yọmi sọrọ siwaju si i pe iwa igberaga atawọn ti wọn n gbe igbesi aye ofege loun ri iru ọrọ bẹẹ si, nitori Naijiria gẹgẹ bii orilẹ-ede gan-an n tọrọ, bẹẹ ni wọn n yawo, ka ma ti i waa sọ eeyan bii tiẹ naa.

Bẹ o ba gbagbe, ninu fidio kan ti Jaiye gbe sori Instagraamu rẹ lo ti sọrọ sawọn onitiata ti wọn n gbegba baara lori ẹrọ ayelujara, o ni ailajẹṣẹku wọn lati ọdun ti wọn ti wa nidii iṣẹ naa lo sọ wọn di alagbe ọsan gangan, ti wọn si n tibẹ ko ẹrẹ ba ẹgbẹ TAMPAN, ati gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ lapapọ.

Oṣere yii ni bi wọn ṣe n ṣe tiata lede abinibi ni tawọn to n sọ Gẹẹsi naa wa, ati pe ko sẹni ti ki i rẹ, ko sẹnikan ti ko ni iṣoro, ko si sẹni naa to kọja adanwo, amọ to jẹ pe wọn maa n yanju ẹ laarin ara wọn ni. O ni ṣugbọn tawọn ẹlẹgbẹ oun lede Yoruba yii lo wa n dun oun, nitori bi wọn ṣe sọ baara di ojulowo iṣẹ, to fi jẹ pe awọn eeyan ti ko pọnmi silẹ de oungbẹ, ti wọn ko si ṣeto ọjọ iwaju wọn kalẹ latari oriṣiiriṣii nnkan ti ko tọ ti wọn n kowo wọn le, wa n fi aṣọ ẹgbẹ awọn yi ẹrẹ, wọn sọ awọn oṣere tiata ledee Yoruba di oniṣẹẹ ati ọdaju eeyan loju araye.

Oriṣiiriṣii iha lawọn eeyan to gbọ ọrọ Jaiye ati Yọmi kọ si ọrọ naa. Bawọn kan ṣe n sọ pe ootọ ọrọ pọnbele ni Jaiye sọ, bẹẹ lawọn kan n sọ pe ọrọ ti Yọmi lo tọna, wọn ni ẹni ija o ba lo n pera ẹ lọkunrin.

Ṣugbọn ju gbogbo rẹ lọ, ohun to han bayii ni pe wahala n lọ lagbo awọn oṣere ilẹ Yoruba nitori awọn kan ko dunnu si bi awọn agba ẹgbẹ naa ṣe di alagbe, ti wọn n tọrọ owo ati mọto. Bẹẹ lawọn mi-in n sọ pe ko sohun to buru ninu rẹ.

 

Leave a Reply