Olu-Theo Omolohun, Oke-Ogun
Ilu Ofiki, nijọba ibilẹ Atisbo, nipinlẹ Ọyọ, gbalejo apapandodo laaarọ ọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja yii, pẹlu bawọn Fulani darandaran kan ṣe ya wọ ilu naa, pẹlu iyawo atawọn ọmọ wọn, bẹẹ si ni maaluu rẹpẹtẹ ti wọn n sin ko gbẹyin, wọn lawọn n wa ibudo tawọn le tẹdo si.
Ẹnikan tọrọ naa ṣoju rẹ ba akoroyin ALAROYE sọrọ lọjọ Aiku, Sannde yii, ni lasiko toun n lọ soko lọjọ Ẹti ọhun loun ri awọn maaluu rẹpẹtẹ lọna Abule Ọbatala ti ko jinna pupọ siluu Ofiki, ṣugbọn ibẹru ko jẹ koun le beere nnkan kan lọwọ awọn Fulani darandaran naa, niṣe loun fọwọ fa eti oun, ere lẹlẹ loun sa de aafin Alagbeere tilu Ofiki, Ọba Baṣhiru Oyeṣiji, lati sọ ohun toju oun ri fun kabiesi.
Nibi tawọn maaluu ati ero naa pọ de, o ni o ju ọgbọn iṣẹju lọ toun fi duro soju kan titi tawọn maaluu naa fi kọja pẹlu awọn Fulani rẹpẹtẹ naa, atọmọde atagba wọn, ti wọn gbe oriṣiiriṣii ẹru ati dukia wọn dani.
Lakooko ti Ọba Oyeṣiji ati ẹlẹgbẹ rẹ, Ọba Sunday Adeoye, Tẹlla kẹta, to jẹ Olọtọ ilu Ofiki, ẹni ti wọn fẹsun kan pe oun lo n ṣe agbodegba fawọn Fulani ti sọ pe ko si ootọ ninu ẹsun ti wọn ka soun lẹsẹ.
O ni adugbo mẹta, pẹlu ọba alade mẹta, ni ilu naa pin si, Ọba Sunday Adeoye lo n ṣakoso Itọ, Ọba Bashiru Oyeṣiji n dari Ageere, nigba ti Ọba Gbenga Adeoye n ṣakoso Sando. Gbogbo awọn ọba yii lo rawọ ẹbẹ sijọba lati tete ba awọn dẹkun awọn Fulani yii, wọn lawọn o fẹ Fulani lagbegbe awọn, awọn ko si ni i faaye gba wọn.
Oloye Joshua Ogundiran to jẹ Jagun ilu Ofiki sọ fakọroyin wa pe agbegbe ilu Igangan lawọn Fulani ọhun ti n bọ, ṣugbọn o da oun loju pe wọn ko le raaye duro si lagbegbe Ofiki tori awọn araalu naa ko ni i gba fun wọn, paapaa awọn agbẹ.