Monisọla Saka
Ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ, ṣiṣe owo ilu mọkumọku atawọn ẹsun to jẹ mọ owo Naira mi-in lorilẹ-ede wa, Economic and Financial Crimes Commission (EFCC), ti ni ọpọlọpọ awọn oṣere ati ilu mọ-ọn-ka mi-in lawọn ti n ṣewadii wọn, aimọye wọn lawọn yoo si ranṣẹ pe fun ifọrọwanilẹnuwo laipẹ nitori ṣiṣe owo Naira baṣubaṣu.
Lẹyin ti ajọ yii ti ran gbajumọ ọkunrin bii obinrin nni, Idris Ọlanrewaju Okunẹyẹ, tawọn eeyan mọ si Bobrisky lẹwọn fun ẹsun to ni i ṣe pẹlu ṣiṣe owo Naira baṣubaṣu ati arọndarọnda owo, ni ileeṣẹ naa ti n wa awọn eeyan mi-in ti wọn ti foju owo ilẹ wa gbolẹ.
Lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ni Dele Oyewale, ti i ṣe olori ẹka iroyin ileeṣẹ naa fi atẹjade sita lori ọrọ yii.
Wọn ni igbesẹ tuntun tawọn ṣẹṣẹ bẹrẹ lati le maa ba awọn to ṣẹ wi yii ko ni i da ẹyọ ẹni kan si.
EFCC mura si ọrọ yii lati le fi awọn eeyan kan jofin, eyi ti yoo jẹ arikọgbọn fawọn eeyan ti wọn ba tun fẹẹ da iru ẹ laṣa. Bẹẹ ni ariwo awọn eeyan lori ayelujara ti wọn n gbe fidio lọlọkan-o-jọkan awọn gbajumọ ati oloṣelu to n fọn owo bii ẹlẹda naa tun n le wọn lere. Fidio loriṣiiriṣii to jẹ ti atijọ ati eyi to ṣẹṣẹ waye ni wọn n pe akiyesi ajọ EFCC si ni gbogbo igba ti wọn ba ti ju u sori ayelujara.
Oyewale ti ko darukọ kan ni pato sọ pe awọn ti ranṣẹ si awọn gbajumọ kan fun ifọrọwanilẹnuwo, wọn si ti ṣe awọn alaye to le ran iṣẹ awọn lọwọ fawọn.
“Ni kẹtikẹti lawọn araalu n pe akiyesi ileeṣẹ wa si oriṣiiriṣii fidio awọn ọmọ Naijiria kaakiri, nibi ti wọn ti n ṣe owo Naira baṣubaṣu.
Ohun ti wọn n ṣe yii fi han pe awọn araalu ti mọ nipa ikede wa ta ko titabuku owo Naira ati ifọwọsowọpọ ta a nilo lati rẹyin iwa ibajẹ yii.
“Titi di akoko yii, ileeṣẹ yii yoo tubọ maa ṣewadii, bẹẹ ni wọn yoo maa fi iya to tọ jẹ ẹni to ba jẹbi lati ile-ẹjọ. Gbogbo awọn fidio to ti waye sẹyin tawọn eeyan lọọ hu jade, to si n ja ran-in lori ayelujara ni a ti ri, bẹẹ lo jẹ ọrọ ẹlẹgẹ, nitori lọjọ keje, oṣu Keji, ọdun yii, ni ikọ amunifọba ti ileeṣẹ EFCC gbe dide lati gbogun ti ṣiṣe owo Naira baṣubaṣu ati fifi owo dọla ba eto ọrọ aje wa jẹ ṣẹṣẹ bẹrẹ iṣẹ. Amọ ṣa o, a ko ni i ṣai wadii awọn fidio tuntun to ṣẹṣẹ jade lẹyin deeti yii, a o ṣewadii finni-finni lori ẹ, a si maa foju iru ẹni bẹẹ bale-ẹjọ.
“Lọwọlọwọ bayii, ọpọlọpọ awọn gbajumọ ẹda ti wọn lọwọ ninu ṣiṣe owo Naira mọkumọku ni ileeṣẹ yii n wadii lọwọ. Pupọ wọn lo ti fọwọsowọpọ pẹlu wa, ti wọn si fun wa lawọn alaye ti yoo ran iwadii wa lọwọ.
Tẹ o ba gbagbe, lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kejila, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ni Onidaajọ Abimbọla Awogbọrọ, ti Ile-ẹjọ giga kan lagbegbe Erekusu Eko, nipinlẹ Eko, dajọ pe ki wọn ju Bobrisky sẹwọn oṣu mẹfa lai fi aaye beeli silẹ fun un.
Idajọ yii ni ọpọ ọmọ Naijiria bu ẹnu atẹ lu pe o ti lagbara ju, lai jẹ pe o ti figba kan ṣeru ẹ ri. Wọn ni ọwọ agbara nijọba lo lori Bobrisky, tabi ki nnkan mi-in wa ninu ọrọ naa.
Awọn kan ti wọn mu apẹẹrẹ idajọ oṣerebirin kan to ṣẹṣẹ n goke bọ, Ọmọseyin Oluwadarasimi, ti wọn gbe lọ sile-ẹjọ loṣu Keji, ọdun 2023, ti wọn si pada dajọ ẹ lọdun yii, sọ pe bi wọn ṣe foju ẹ rare to, adajọ pada yọnda beeli ẹgbẹrun lọna ọọdunrun Naira (300,000) fun un dipo ẹwọn oṣu mẹfa ni.
Nitori ikanra ọrọ Bobrisky yii lawọn eeyan fi lọọ hu fidio awọn oṣere mi-in, gbajumọ lawujọ atawọn eekan nidii oṣelu, nibi ti wọn ti n fọn owo, ti wọn n ṣe e baṣubaṣu, lojuna ati le jẹ kawọn naa foju wina ofin.