Wahala n bọ o, Ẹgbẹ APC Ondo jawee gbele-ẹ fun Sẹnetọ Jimoh Ibrahim

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress ti jawee gbele-ẹ fun sẹnetọ to n ṣoju awọn eeyan ẹkun Guusu ipinlẹ Ondo, Sẹnetọ Jimoh Fọlọrunṣọ Ibrahim, lori bo ṣe pẹjọ ta ko ikede Gomina Lucky Ayedatiwa gẹgẹ bii ẹni to yege ninu eto idibo abẹle ẹgbẹ ọhun ti wọn di l’ogunjọ, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 ta a wa yii.

Awọn aṣaaju ẹgbẹ APC ni Wọọdu keji, eyi to wa niluu Igbotako, nijọba ibilẹ Okitipupa, ti i ṣe ilu abinibi Ibrahim ni wọn ṣe ikede yii l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii.

Awọn asaaju ọhun ni awọn gbe igbesẹ yii nitori iwa afojudi rẹ pẹlu awọn igbesẹ to lodi si ilana ẹgbẹ to n gbe lọwọlọwọ.

Ibrahim to jẹ ọkan ninu awọn oludije mẹrindinlogun ti wọn kopa ninu eto idibo abẹle ọhun lo lọọ pẹjọ ta ko eto idibo naa nile-ẹjọ giga kan to fikalẹ siluu Abuja, nibi to ti n bẹbẹ fun fifagi le eto idibo ọhun, eyi to ni ọpọlọpọ aiṣe deedee lo wa ninu rẹ.

Ki eto idibo abẹle ọhun too waye lawọn aṣaaju ẹgbẹ APC ti gbe igbimọ kan kalẹ, wọn lawọn ọmọ igbimọ yii ni yoo yanju gbogbo awuyewuye yoowu to ba su yọ lati inu eto idibo naa.

Kete ti wọn si ti pari eto idibo ọhun lawọn oludije bii meloo kan ti mu ẹjọ lọ sinu igbimọ ko-tẹ-mi-lọrun naa, ṣugbọn si iyalẹnu gbogbo awọn to lọ, ṣe ni wọn da ẹjọ wọn nu, ti wọn ni ko lẹsẹ nilẹ.

Lẹyin eyi ni alaga ẹgbẹ APC lorilẹ-ede yii, Abdullahi Ganduje, pe gbogbo awọn to kopa ninu eto idibo naa si ipade pataki kan l’Abuja, to si parọwa si gbogbo wọn lati fọwọ wọnu, o ni ki wọn gba abajade eto idibo abẹle naa, ki wọn si fọwọsowọpọ pẹlu Ayedatiwa ti wọn kede pe o yege, ki ẹgbẹ awọn le rọwọ mu ninu eto idibo to n bọ lọna.

Ṣugbọn o da bii ẹni pe abọ ipade Abuja ko tẹ Ibrahim lọrun, leyii to mu ko lọọ pẹjọ si kootu kan l’Abuja, nibi to ti n beere fun pe ki wọn fagi le eto idibo abẹle naa, tabi ki wọn yọ orukọ ẹgbẹ APC kuro ninu awọn ti yoo kopa ninu eto idibo gomina to n bọ lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2024 yii, nitori ko si eto idibo kankan to waye nibikibi l’ogunjọ, oṣu Kẹrin, yii.

Awọn mẹta, ninu eyi ta a ti ri ẹgbẹ APC, ajọ eleto idibo ati Ayedatiwa funra rẹ ni Ibrahim pe lẹjọ, ọjọ Isẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrinla, oṣu Karun-un yii ni kootu fi igbẹjọ akọkọ si, ti adajọ kootu ọhun si paṣẹ lẹyin-o-rẹyin fawọn mẹtẹẹta ti wọn pe lẹjọ lati tete wọna ati fesi lori awọn ẹsun ti wọn fi kan wọn.

Lẹyin gbogbo atotonu yii ni adajọ sun igbẹjọ mi-in si inu oṣu Kẹfa to n bọ yii.

 

Leave a Reply