Wahala n bọ o, Gomina Adeleke yọ adajọ to ran Rahman Adedoyin lẹwọn nipo

Florence Babaṣọla Oṣogbo

Pẹlu bi nnkan ṣe n lọ, afaimọ ki wahala ma  ṣẹlẹ laarin ileesẹ eto idajọ ati Gomina ipinlẹ Ọsun, Ademọla Adeleke pẹlu bi gomina yii ṣe kọ lati tẹle aṣẹ ti ile-ẹjọ pa lori yiyọ Adajọ agba ipinlẹ naa, Abilekọ Adepele Ojo nipo.

Laipẹ yii ni ahesọ n lọ kaakiri pe ijọba fẹẹ yọ Adajọ-agba, Adepele Ojo, ni tipatipa kuro nipo, ṣugbọn kia ni Kọmiṣanna fun eto iroyin, Kọlapọ Alimi, jade, to si ni ijọba ko mọ si nnkan ti wọn n sọ naa.

Bakan naa ni agbarijọpọ awọn ẹgbẹ to n ja fun ẹtọ ọmọniyan nipinlẹ Ọṣun sọ pe oniruuru ẹsun ni ijọba ti we mọ Adepele lọrun lati le fi yọ ọ nipo, bẹẹ ni wọn si ti kọwe ẹsun si ajọ to n ri si ọrọ awọn adajọ, (NJC), nipa rẹ, sibẹ, ijọba sọ pe irọ ni.

Lati le ṣe ọrọ naa ni koju ma ribi, gbogbo ara loogun ẹ lo mu ki Adepele Ojo mori le ile-ẹjọ to n ri si ọrọ awọn oṣiṣẹ, National Industrial Court, to wa niluu Ibadan, lati le ka ijọba Ọṣun lọwọ ko lori igbesẹ ti wọn fẹẹ gbe lati yọ ọ kuro nipo.

Ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kọkanla, ọdun yii, ni Adepele gbe iwe ẹsun lọ sibẹ, nibi to ti pe Gomina Adeleke, ajọ to n ri si ọrọ awọn adajọ, kọmiṣanna fun ọrọ ofin ati oluṣiro owo agba nipinlẹ Ọṣun lẹjọ.

Ninu idajọ lori ẹjọ ọhun ti Onidaajọ Peters to gbe kalẹ lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kọkanla, ọdun yii, lo ti paṣẹ pe ijọba ko gbọdọ da Adepele duro, wọn ko gbọdọ gba iṣẹ lọwọ rẹ, bẹẹ ni wọn ko gbọdọ da owo-oṣu atawọn ajẹmọnu rẹ duro.

Ṣugbọn ọsan ọjọ yii kan naa ni awọn ọmọ ileegbimọ aṣofin Ọṣun sọ pe awọn ri iwe ẹsun oniruuru gba nipa Adepele, wọn ni ko yọju si awọn laarin ọjọ meje lati ṣalaye ẹnu rẹ lori awọn ẹsun naa.

Awọn aṣofin sọ pe niwọn igba ti ko ti gbọdọ si alafo ni ọfiisi naa, ki gomina yan onidaajọ to tẹle Adepele nipo gẹgẹ bii adele.

Kia naa si ni Agbẹnusọ fun gomina, Mallam Rasheed Ọlawale, ti gbe atẹjade sita lorukọ gomina pe Adeleke ti fọwọ si yiyan Onidaajọ Ọlayinka Afọlabi gẹgẹ bii adele adajọ agba.

Ọlawale ṣalaye pe gomina yoo bura fun Afọlabi lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kọkanla, ọdun yii, nibaamu pẹlu aṣẹ ile igbimọ aṣofin.

Ni bayii, Gomina ipinlẹ Ọṣun, Sẹnetọ Ademọla Adeleke, ti kede Onidaajọ Ọlayinka David Afọlabi gẹgẹ bii adele adajọ agba funpinlẹ naa.

Leave a Reply