Monisọla Saka
Ẹka ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko keji, to n ṣewadii iwa ọdaran, Criminal Investigation Department, (CID), to wa ni Alagbọn, Ikoyi, nipinlẹ Eko, ti ranṣẹ si Ọgbẹni Joseph Alọba, ti i ṣe baba ọmọkunrin olorin taka-sufee to ku lọdun to kọja, ti wọn si n wadii ohun to ṣokunfa iku rẹ lati ọjọ yii, Ilerioluwa Ọladimeji Alọba, tawọn eeyan mọ si Mohbad.
Ninu lẹta ti wọn fi ṣọwọ si adirẹsi ile baba naa to wa ni 8, Cele Okeletu, Powerline, Ijẹdẹ, Ikorodu, nipinlẹ Eko, ni wọn ti ni ko yọju sileeṣẹ awọn laago mẹwaa aarọ ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹta, oṣu yii, fun iwadii lori ẹsun idunkooko mọ ni lori ayelujara ti wọn fi kan an.
Lẹta ti wọn fi ranṣẹ pe Ọgbẹni Alọba ka bayii, “Ileeṣẹ to n ri si iwadii iwa ọdaran nipinlẹ Eko, n ṣewadii ẹsun idunkooko mọ ni lori ayelujara (cyberbulling), itọpinpin eeyan lori afẹfẹ (cyber stalking) ati iwa ibanilorukọ jẹ, pẹlu ẹsun iwa ọdaran, nilo iwadii awọn nnkan kan to ṣe pataki lati ọdọ yin.
“O ṣe pataki ki ẹ yọju si ileeṣẹ keji ikọ agbofinro to n wadii iwa ọdaran nipinlẹ Eko, (CID Annex), to wa ni Alagbọn close, Ikoyi, nipinlẹ Eko, laago mẹwaa aarọ ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹta, oṣu Kẹfa yii.
Ni kete ti ẹ ba ti de, SP Sarumi Idris, ti ikọ to n ṣe iwadii pataki, Special Investigation Team (SIT), ni ẹka to n gbogun ti iwa jibiti lilu, Anti Fraud Section, ni ẹ oo yọju si ti yoo da yin lohun.
“Iwadii ijinlẹ ti ijọba ati ofin ilẹ Naijiria, abala igba o le mẹrinla (214), ti ọdun 1999, ati ikẹrin, ri ọdun 2000, gbe agbara rẹ wọ ileeṣẹ ọlọpaa ni eyi.
Wiwa yin yoo ran wa lọwọ lori idajọ ododo ti a n fẹ.
Bakan naa ni ẹ lanfaani lati wa pẹlu agbẹjọro yin”.
Bayii ni lẹta ipeni fun ifọrọwanilẹnuwo ti wọn kọ si Baba Mohbad naa ṣe lọ.
Awọn to mọ bo ṣe n lọ sọ pe bi awọn ọtẹlẹmuyẹ ṣe ranṣẹ pe Alagba Alọba ko ni i ṣeyin awọn ifọrọwerọ oriṣiiriṣii ti ọkunrin naa n ṣe lẹnu ọjọ mẹta yii lori ayelujara ati ninu iweeroyin, nibi to ti n fẹsun kan awọn eeyan kan ati ipa ti wọn ko lori iku ọmọ rẹ, paapaa ju lọ iya oloogbe, iyawo rẹ ati awọn mi-in ti oloogbe naa ba ṣiṣẹ pọ bii Sam Larry ati bẹẹ bẹẹ lọ.