Adewale Adeoye
Titi di akoko ta a n ko iroyin yii jọ, ko sẹni to mọ ibi ti dugbẹ-dugbẹ ọrọ ija kan to n ru labẹnu laarin gbajumọ olorin Hipọọpu nni, Abeeb Okikiọla, ẹni tawọn eeyan mọ si Portable, ati igbakeji ọga awọn ọmọ ẹgbẹ onimọto nipinlẹ Eko, Alhaji Koko Zaria, maa ja si bayii. Ohun kan to daju ṣaka ni pe Portable ko mu ọrọ naa ni kekere, ariwo buruku lo n pa, to si n ṣe fidio ọlọkan-o-jọkan sori ayelujara lati fi aidunnu rẹ han si iṣẹlẹ naa. Ẹni ba si ri i bi ọmọkunrin naa ti n fẹfun foo, to n laagun nimu lori ẹsun to fi kan Koko Zaria pe o gba iyawo oun, tọhun yoo mọ pe kinni ọhun ko wọ ibi to daa lara ọmọkunrin olorin naa. Ileri ti Portable n le bayii ni pe oun ko sọ pe ki Koko Zaria ma ba iya ọmọ oun sun gẹgẹ bi wọn ṣe ti n ṣe bayii, ṣugbọn ko ma daa laṣa rara lati gba ọmọ oun ti ale rẹ maa n gbe waa ba nibi ti wọn ba fi ipade si.
Ninu fidio ti ọmọkunrin olorin ti wọn n pe ni Zaa-Su-Zeh gbe sori ayelujara lo ti ki epe nla bọnu, to si n fọwọ gb’aya pe ko s’ohun ti Koko Zaria le foun ṣe nitori pe oun paapaa ki i ṣe ẹran rirọ rara.
O ni, ‘‘Ẹ wo, ẹ ba mi kilọ fun Koko Zaria gidi o, mi o sọ pe ko ma ba iya ọmọ mi sun, ṣugbọn ẹ sọ fun un pe ko yee gbọwọ le ọmọ mi lori mọ. Iyawo ọlẹ ni wọn n gba, ko sẹni to maa gbọmọ ọlẹ lae. Emi ni mo lọmọ mi, maaluu ni mo si pa lọjọ ta a maa ko ọmọ ọhun jade. Iya ọmọ ọhun lo jẹ oniranu obinrin, bawo lo ṣe maa gbe ọmọ mi lọ sọdọ ale rẹ ti i ṣe Koko Zaria, Koko Zaria naa aa waa ra bisikiiti atawọn oriṣiiriṣii ohun ipanu f’ọmọ temi lotẹẹli ti wọn ba gbe ara wọn lọ. Ọmọ ọhun ṣi kere lọjọ ori ju ohun ti iya rẹ n gbe e lọọ ṣe yii kẹ.
Ka tiẹ sọ pe oloriboobo ni iya ọmọ mi to n gbe ọmọ ọdun kan pere lọ sotẹẹli yii, ṣe oju ko ṣọna fun Koko Zaria paapaa ni pe ọmọ ti ale rẹ n gbe waa b’oun lotẹẹli ṣi n mu ọmu lọwọ, ẹ sọ fun iya ọmọ naa pe ko maa gbiyanju lati gbe ọmọ mi silẹ sọdọ ẹnikan to ba ti fẹẹ lọọ ba Koko Zaria tabi ale rẹ yoowu to ba fẹẹ lọọ ba a.
Gbogbo ohun to yẹ ki n ṣe gẹgẹ bii ojulowo baba ọmọ ni mo n ṣe lori ọmọ mi. Ṣugbọn obinrin to ba maa ya oniranu aa ya a lọrọ rẹ, ko jọ mi l’oju rara, ṣugbọn ẹ ṣaa kilọ fun Koko Zaria pe ko ṣọra ṣe o, mi o ki i ṣẹni ti wọn maa yan jẹ lasan. Oogun n bọ f’ohun to ṣe si mi yii, oju M.C Oluọmọ, iyẹn ọga nla, ẹni to jẹ ọga Koko Zaria ni mo n ti o, M.C lo pe mi sode Oshodi-Day, bi ki i baa ṣe pe mo lọ sibẹ ni, oju mi ko ni i ri radarada yẹn rara, ṣugbọn o daa bẹẹ naa, oju mi ni mo fi ri ohun to n ṣẹlẹ lọjọ naa, ki i ṣe pe ẹnikan lo waa ṣofofo fun mi.
Emi paapaa ko mọ pe iya ọmọ mi yii gbọpọ bẹẹ yẹn o, nita gbangba ni Koko Zaria to jẹ ale rẹ waa n kẹnu bọ ọ lẹnu bẹẹ yẹn. Aṣe aṣẹwo ni ẹni to bimọ fun mi yii. Oniranu nla gbaa ni kẹ. Iwọ too n gbadun lọdọ mi lo waa n tẹle Koko Zaria to jẹ pe ọmọ onimọto lasan ni, agbero ti ko lọjọ ọla gidi. O filuu mọ-ọn-ka silẹ, o waa n lọ gbe idi fun oloṣi eeyan kan, ṣiọ rẹ.
Ṣugbọn Koko Zaria naa ti fun Portable lesi o, bo tilẹ jẹ pe ki i ṣe pe o sọrọ kankan fun un, orin Pasuma lo gbe sori fidio kan to gbe jade. Orin ti Pasuma kọ pe awọn ti kọja gbogbo iyẹn ni ọkunrin naa gbe si i, to fi n fun Portable lesi.