Monisọla Saka
Ọrọ ti wọn pe lowe ti n laro ninu bayii pẹlu bi Portable olorin, ọkan ninu awọn ti oluṣọ ijọ Sẹlẹ kan pe lati waa kọrin nibi eto pataki kan ti wọn fẹẹ ṣe, eyi ti wọn pe ni (Ankara Praise Night), ti yoo waye lọjọ kẹẹẹdogun, oṣu yii, ṣe yari pe afi dandan ki oun waa kọrin nibi eto naa, nitori awọn ṣọọṣi yii lo fiwe pe oun, wọn si ti san miliọnu marun-un toun beere fun, nipa bẹẹ, yẹkinni kan ko le yẹ ẹ, oun maa kọrin nibẹ, bo tilẹ jẹ pe awọn ijọ naa ti ni awọn ko gbọdọ ri i ko wa sibi eto yii.
Eto naa, eyi ti wọn ti pe gbajumọ olorin Fuji nni, Alabi Pasuma, ati Portable olorin, si ni awọn ọmọ ijọ ati agbaagba Sẹlẹ kan koro oju si pe ki i ṣe ohun to dara lati pe iru awọn olorin bẹẹ si iru eto ti wọn fẹẹ ṣe yii. Wọn ni awọn olorin Onigbagbọ wa nilẹ to yẹ ki wọn pe to le waa kọrin fun wọn nibẹ.
Oluṣọ agba fun ijọ Celestial Church of Christ, to wa lagbegbe Ketu, nipinlẹ Eko, Ọlatọshọ Ọshọffa, lo kọkọ koro oju si ọkan ninu awọn ẹka ijọ wọn to gbe eto ti wọn pe ni ‘Aṣaalẹ Iyin’ (Ankara/Praise Night), kalẹ. Ki i ṣe pe eto ọhun ni Oluṣọ naa n binu si bi ko ṣe awọn elere ti wọn pe fun eto ti wọn fẹẹ ṣe ọhun.
Gbajugbaja olorin Fuji nni, Alaaji Wasiu Alabi, tawọn eeyan mọ si Pasuma, ati ọkunrin olorin taka-sufee to gba igboro kan nisinyii, Habeeb Okikiọla Ọmọlalọmi, ti gbogbo eeyan n pe ni Portable Zaazu Zeh, ni wọn pe gẹgẹ bii olorin si ile ijọsin ọhun.
Gbara ti iwe ikede eto ti aworan Pasuma ati Portable wa ninu ẹ yii ti gba ori ẹrọ ayelujara kan l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun yii, lawọn eeyan ti n sọrọ buruku si ijọ naa ati awọn to wa nidii eto ọhun, nitori iru awọn olorin ti wọn pe sibẹ. Wọn ni kin ni awọn olorin Fuji ati Portable n ṣe nibi eto to jẹ mọ ṣọọṣi, nigba ti ki i ṣe pe wọn ko ri awọn olorin Kirisitẹni nilẹ to le waa kọrin fun wọn.
Lọjọ Wẹsidee ọhun kan naa, ni Ọshọffa, ti i ṣe Oluṣọ ati olori ṣọọṣi Cele ti gba oju opo ibanidọrẹẹ Facebook rẹ lọ. Nibẹ lo ti ṣalaye pe oun ti ba pasitọ ẹka ijọ naa sọrọ, ati pe awọn olorin to wa ninu iwe ipe ọhun kọ ni yoo kọrin nibẹ mọ.
“Ẹyin ọmọ olu ijọ mimọ Celestial, mo ti ba Oluṣọ to n ṣakoso ijọ yẹn sọrọ. O si ti ṣeleri fun mi lati ṣe atunṣe. O ti ni awọn elere ti wọn fọnrere wọn tẹlẹ yẹn ko ni i wa fun isin alẹ ọjọ yẹn mọ”.
O ni posita ti wọn n lẹ kiri yẹn jẹ nnkan idojuti ti ko bojumu nitootọ lati pe awọn ti wọn n kọ iru orin yii siru ajọdun bẹẹ. Bẹẹ lo ṣadura pe ki Ọlọrun tubọ bukun fun ijọ Celestial.
Ṣaaju asiko yii ni Portable olorin, ọkan ninu awọn ti wọn fiwe pe lati waa ṣere nibẹ ti gbe ọrọ naa sori ayelujara, to si n pe gbogbo awọn eeyan pe ki wọn waa pade oun ninu ijọ Sẹlẹ naa, nibi ti oun ti maa forin aladun da wọn laraya.
Ohun ti Oluṣọ yii sọ ni wọn lo bi Portable ninu, to si fi fi dandan le e pe afi ki oun kọrin ni ṣọọṣi naa. Ninu fidio kan ti ọmọkunrin olorin ti wọn n pe ni Zah Zuh yii gbe jade lati fesi si ipinnu awọn olori Sẹlẹ yii lo ti sọ pe, ‘‘Ẹyin Ṣẹlẹ, a maa ṣere yẹn o, ẹ ti tẹ owo o, miliọnu marun-un, a dẹ maa ṣe e. Pasuma maa wọle, emi naa maa wọle, a dẹ maa ṣere yẹn.
‘‘Ẹ gba mi o, wọn o fẹ ki ọmọ Ọlọrun wọ ṣọọṣi o. Pasitọ to ni ki n ma wọ ṣọọṣi, ṣe owo rẹ ni wọn fi kọ ṣọọṣi ni, ṣebi awọn ọmọ ijọ lo dawo jọ ti wọn fi kọ ṣọọṣi, ki i ṣe dukia pasitọ, dukia Ọlọrun ni, ẹ waa ni ka ma wa si ṣọọṣi. Ka ma baa waa gba ororo, ka ma baa waa gba ọṣẹ, lọdun tuntun 2024, ṣe awọn ọmọ yin nikan lẹ fẹ ki wọn maa lo o, a maa ba yin lo o, a maa tun irapada ṣe, a maa lọ si ori oke, a o ni i ja bọ…
‘’Ẹyin Ṣẹlẹ, ẹ da wa mọ ọmọ tọ, ọmọ Ọlọrun lawa naa. Ṣe awọn ọmọ yin naa ki i lọ si kilọọbu, ṣe wọn o ki i gbọmọ. Wọn ni temi ba to bẹẹ ki n wa, emi maa wa, emi Ifa Olúmopè. Ṣe ẹ ro pe emi da bii awọn ti ẹ maa n ṣe ti wọn maa n ṣubu yẹn ni, emi o lẹ ṣubu o… Wọn o fẹ ki Ika wọ ṣọọṣi ki aṣiri ma lọọ tu. Wọn o fẹẹ ṣeka yẹn loju mi ni, mo dẹ maa wa… Pasitọ ni mi, ẹ maa wa si ijọ temi naa, ẹ maa waa gbọ ọrọ Ọlọrun. Ṣe awọn pasitọ ko ki i lọ si kilọọbu, ṣe wọn o ki i gbọmọ…’’
‘‘Land of Goshen Cathederal, ẹ jọwọ tori Ọlọrun, ẹ foju ọmọ Ọlọrun wo wa. Ẹ ma fi bi irisi mi ṣe ri da mi lẹjọ. Ẹ jọwọ, mo fi Ọlọrun bẹ yin. Ṣebi jẹẹjẹ mi ni mo jokoo tawọn Sẹlẹ pe mi ki n waa kọrin fun wọn, ẹyin lẹ fowo pe wa. Aimọye awọn ilu-mọ-ọn-ka olorin to jẹ pe Sẹlẹ ni wọn’’.
Ọrọ ti Portable sọ yii ti da wahala nla silẹ laarin awọn adari Ṣẹlẹ atawọn ọmọ Ṣẹlẹ lapapọ, nitori awọn adari ijọ naa gbe igbimọ kan dide lati wadii ọrọ lẹnu oluṣọ ijọ wọn to pe Pasuma ati Portable lati waa kọrin. Ohun ti oluṣọ naa sọ ni pe ki oun le baa jere ọkan loun fi pe awọn eeyan naa lati waa kọrin. O fi kun un pe oriṣiiriṣii awọn olorin loun ti lo, ṣugbọn lati pe awọn alaigbagbọ wa, ati lati jere ọkan wọn ni oun ṣe pe awọn olorin yii.
Ṣugbọn ọpọlọpọ awọn ọmọ Ṣẹlẹ ni wọn ti n jade sita, ti wọn si n kilọ pe awọn ko fẹẹ ri Portable nibi eto naa ti ko ba fẹẹ ri ibinu Ọlọrun. Ọmọkunrin kan to pe ara rẹ ni Emmanuel ni ki Portable ma tiẹ dan an wo rara, nitori ohun to maa ti ẹyin rẹ yọ fun un ko ni i daa.
Ọrọ naa ti di wahala nla bayii, bawọn kan ṣe n sọ pe ko sohun to buru ninu ohun ti Oluṣọ to pe Portable ati Pasuma ṣe, bẹẹ lawọn mi-in n sọ pe ohun to buru jai ni lati maa pe awọn olorin bẹẹ sinu ijọ Ọlọrun.
Ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu yii, ti eto naa yẹ ko waye lawọn eeyan n reti boya Portable yoo kọrin nibẹ tabi ko ni i kọrin.