Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ẹgbẹ kan ti wọn pe ara wọn ni ẹgbẹ Ọmọ Ilajẹ, ti kọwe ẹbẹ ranṣẹ si Arakunrin Rotimi Akeredolu ti i ṣe Gomina ipinlẹ Ondo lori igbesẹ ti wọn lawọn eeyan kan n gbe lati yẹ aga mọ Igbakeji rẹ, Ọnarebu Lucky Orimisan Ayedatiwa, nidii.
Ẹda lẹta ọhun, eyi ti Igbakeji adari ẹgbẹ, Ọgbẹni Ọla Ajidibo, buwọ lu, ni wọn fi ṣọwọ sawọn oniroyin l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ keje, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii.
Ajidibo ni ko si iroyin aburu kan tawọn eeyan n gbọ nipa ipinlẹ Ondo tẹlẹ, ṣùgbọ́n ohun to n kọ awọn lominu ni pe nnkan ti fẹẹ maa yipada nitori ohun tí wọn n gbọ nipa ipinlẹ naa ki i ṣohun to dun mọ awọn ninu rara.
O ni aisinile Aketi ti n fun awọn ọlọtẹ kan lanfaani lati ja iṣakoso ijọba gba, ti wọn ti fẹẹ sọ ọfiisi igbakeji gomina di yẹpẹrẹ.
O ni idi ree to fi ṣe pataki lati tete pe akiyesi Akeredolu si ọkan-o-jọkan awọn iṣẹlẹ ti ko bojumu to n waye lọwọlọwọ nipinlẹ rẹ, eyi to kan ọkan ninu awọn ọmọ Ilajẹ gbọngbọngbọn.
Ọkunrin ọhun ni o da awọn ti awọn jẹ ẹgbẹ ọmọ Ilajẹ loju to ada pe Arakunrin ko ti i gbagbe atilẹyin to ri gba lati ẹkun awọn, ati pe awọn eeyan agbegbe naa ko le sọ bí inu wọn ṣe dun to nigba tijọba apapọ fun ipinlẹ Ondo niwee-ẹri to faaye gba kikọ ibudokọ oju omi si agbegbe Ilajẹ.
O ni igbesẹ tawọn gbọ pe awọn ọbayejẹ kan n gbe lọwọ lati yọ Ayedatiwa ti i ṣe igbakeji gomina kuro nipo n kọ awọn eeyan ipinlẹ Ondo to nironu lominu.
Eyi lo ni o fara han gbangba pẹlu bi Olori awọn aṣofin tuntun ti wọn ṣẹṣẹ yan, Ọladiji Ọlamide, ṣe mọ-ọn-mọ kọ lati darukọ igbakeji gomina ninu ọrọ ikini rẹ gẹgẹ bii alakalẹ ofin.
O ni ohun to tumọ si ni pe ṣe ni wọn mọ-ọn-mọ fẹẹ yọ ọwọ kilanko awọn eeyan Ilajẹ kuro ninu eto oṣelu ipinlẹ Ondo, ti awọn ọlọtẹ ọhun ba si n tesiwaju lati maa yẹyẹ igbakeji gomina gẹgẹ bi wọn ti n ṣe lọwọ.
Ajidibo ni awọn n gbadura kikan kikan ki Ọlọrun tete fun Akeredolu lalaafia, ki ohun gbogbo le pada bọ sipo nipinlẹ Ondo.
Lati ọsẹ kan sẹyin ni ọkan-o-jọkan awuyewuye ti n waye lori eto iṣakoso ijọba ipinlẹ Ondo latari ara Gomina Akeredolu ti ko ya.
Ohun tọpọ awọn eeyan ipinlẹ ọhun si n sọ ni pe ko si eewọ ninu ọrọ aisan to n ba Aketi finra, niwọn igba to jẹ pe eeyan ẹlẹ́ran ara ni.
Ohun tawọn eeyan n bu ẹnu atẹ lu ninu iwa gomìna ọhun ni bo ṣe kọ lati fa eeku iṣakoso ipinlẹ naa le Igbakeji rẹ, Ọnarebu Lucky Orimisan Ayedatiwa, lọwọ.
Ibẹrẹ oṣu Kẹrin, ọdun yii, ni Arakunrin kọ lẹta si olori ile-igbimọ aṣofin Ondo pe oun n lọ fun ìsinmi ọlọ́jọ́ mẹẹẹdogun ọlọdọọdun oun, eyi ti yoo bẹrẹ lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹta, sì ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun 2023.
Gomina ọhun sọ sinu lẹta naa pe oun ti fa eto ìṣàkóso ijọba le Ọnarebu Lucky Orimisan Ayedatiwa ti i ṣe igbakeji oun lọwọ, ẹni ti yoo jẹ Adele-Gomina titi ti oun yoo fi pada de.
Bo ṣe ku diẹ ki asiko ìsinmi naa pari ni Aketi tun sare kọ lẹta mi-in nipasẹ Akọwe iroyin rẹ, Richard Ọlatunde, to si ni oun sun ọjọ to yẹ ki oun waa wọṣẹ pada siwaju, latari ọlude ọjọ meji ti ijọba apapọ kede rẹ fun itunu aawẹ.
Ninu lẹta ti Ọlatunde kọ lorukọ ọga rẹ naa lo ti ni ọjọ kin-in-ni, oṣu Karun-un, ni yoo pada ṣẹnu iṣẹ, dipo ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kẹrin.
ALAROYE gbọ pe Arakunrin sare yọju laarin ọsẹ akọkọ ninu oṣu Karun-un, loootọ, amọ ko fara han nita gbangba ju ẹẹkan pere lọ tawọn eeyan ko tun fi ri i ko jade mọ, bẹẹ ni ko si fa eeku ida ìṣàkóso le igbakeji rẹ lọwọ ko too lọ.
Ko sẹni to le sọ pato ohun to fa wahala laarin Aketi ati igbakeji rẹ to fi kọ lati fa ijọba le e lọwọ ko too lọ fun itọju.