Gbenga Amos, Abẹokuta
Wahala ọwọngogo owo Naira tuntun ati ipenija airi owo atijọ paarọ, tawọn banki ko si gba owo ọhun lọwọ araalu mọ ti tun gba ọna mi-in yọ o. Niṣe lawọn ọdọ tinu n bi lọọ dana sun banki meji laaarọ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, niluu Ṣagamu, nijọba ibilẹ Ṣagamu, nipinlẹ Ogun.
Ba a ṣe gbọ, lati nnkan bii aago meje owurọ lawọn ọdọ naa ti kora jọ, ti wọn si n reti pe kawọn oṣiṣẹ banki naa bẹrẹ iṣẹ, ki wọn ko owo sẹnu ẹrọ ipọwo ATM wọn, tori jalẹ opin ọsẹ ta a lo pari yii, wọn ni ko si eyikeyii ninu awọn ẹrọ naa to ṣiṣẹ, awọn araalu ko ri owo tuntun naa, bẹẹ ni wọn o ri igba Naira atijọ ti ijọba ṣeleri lati ko boode.
Amọ niṣe nireti awọn ọdọ dana yii ja si pabo pẹlu bi awọn banki naa ko ṣe ṣilẹkun, ti oṣiṣẹ ko si wọle, bẹẹ ni wọn o ri ẹnikẹni lati da wọn lohun tabi ba wọn sọrọ, niṣe lawọn ẹṣọ alaabo to n sọ ọgba naa ti gbogbo geeti wọn pinpin.
Ikanra eyi lawọn ọdọ naa fi fariga lojiji ni wọn bẹrẹ si i dana sun taya laarin titi ati lẹgbẹẹ titi, wọn n fibinu sọrọ fatafata pe awọn ko le fara mọ ilaalaṣi ati inira tawọn n koju lori owo tawọn tọju si banki.
Kẹnikẹni si too mọ ohun to n ṣẹlẹ, awọn kan lara wọn ti yọ irin si ẹrọ ATM, wọn fọ gilaasi oju awọn maṣinni naa, wọn ba a jẹ, ni wọn ba sọ taya ti wọn ti fi epo bẹntiroolu wọn sinu ọgba ile naa, wọn ṣana si i. Ninu fidio kan to n ja ranyin lori ẹrọ ayelujara, a ri i bi ina ọmọ ọrara ṣe n jo bulabula lara ile naa.
Ohun kan naa si ni wọn ṣe ni Union Bank to wa lagbegbe Ijoku, niluu Ṣagamu, wọn dana sun oun naa, wọn si ba awọn dukia olowo iyebiye jẹ.
Lẹyin eyi lawọn olufẹhonuhan naa kora jọ si Sẹkiteria ijọba ibilẹ Ṣagamu, wọn ba aga, teburu atawọn nnkan eelo ijọba to wa nibẹ jẹ patapata.
Bi wọn ṣe n ṣetan nibẹ, wọn tun mori le ile ijọba to wa ni Ita-Ọba, lagbegbe GRA, eyi si ṣediwọ fun igbokegbodo ọkọ loju popo lagbegbe ọhun.
Ẹnikan tiṣẹlẹ naa ṣoju ẹ sọ pe awọn eeyan yii tun de First Bank to wa ni Sabo, wọn si fọwọ ba oun naa, wọn ba awọn dukia wọn jẹ.
Amọ, ba a ṣe gbọ, ko pe tawọn oṣiṣẹ ileeṣẹ panapana agbegbe naa fi de ibi iṣẹlẹ yii, pẹlu awọn ọlọpaa atawọn ṣọja, wọn pa ina naa, bawọn ọdọ naa si ṣe ri awọn agbofinro toju wọn n tu bii ejo yii ni kaluku ti wabi gba.
Niluu Abẹkuta ti se olu ilu ipinlẹ Ogun, o le lẹgbẹrun kan awọn eeyan to wa ni ile ifowopamọ lati paaro owo atijọ ọwọ wọn si tuntun, leyii ti ko ṣee ṣe. Bakan naa lawọn eeyan to wa nidii ATM lati gba owo ko ri i gba, latari bi awọn oṣiṣẹ banki naa ko ṣe fi owo sinu ẹrọ ipọwo wọn.
Ni bayii, Akarigbo tilẹ Rẹmọ, Ọba Babatunde Ajayi, ti parọwa sawọn olugbe Ṣagamu lati ma ṣe ifẹhonu han kankan mọ, o ni ijọba yoo wa nnkan ṣe si ọrọ ọwọngogo owo to n ba wọn finra naa.
Kabiyesi tun pasẹ fawọn ọlọja lati maa gba owo atijọ naa lọwọ awọn araalu. Oni oun mọ pe ko sẹni ti ko ni i rowo ọhun na.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ko ti i fidi iṣẹlẹ yii mulẹ latari bo ṣe loun yoo pe wa pada lori aago nigba ta a kan si.