Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ọba Abdulrosheed Adewale Akanbi ti i ṣe Oluwoo ti ilu Iwo, ti sọ pe nibi ti nnkan ba ti dara, ti orileede si ni awọn adari gidi, ko yẹ ki Gomina banki apapọ ilẹ wa, Godwin Emefiele, ṣi wa lọfiisi rẹ.
Ọba Akanbi ṣalaye pe ijọloju lo jẹ pe wọn le ko gbogbo owo atijọ kuro nilẹ patapata lai ṣeto owo tuntun ti awọn araalu yoo maa na.
Oluwoo, ẹni to sọrọ yii lasiko to n gbalejo awọn ọmọ orukan, awọn to ku diẹ kaato fun atawọn akanda ẹda laafin rẹ layaajọ ọjọ ololufẹ, sọ pe inira ti awọn ọmọ orileede yii n dojukọ bayii ki wọn too ri owo na ti pọ ju.
O ni ko si irọ ninu ọrọ Sultan Ṣokoto, Alhaji Sa’ad Abubakar, ẹni to sọ pe ebi n pa awọn ọmọ Naijiria, inu si n bi wọn gidigidi, o ni iya n jẹ awọn ọmọ orileede yii labẹ ijọba to wa lode.
Oluwoo ni bawo ni ko ṣe ni i si olori ti yoo fi aidunnu rẹ han si bi Godwin Emefiele ṣe wa lọfiisi titi di asiko yii.
O ke si awọn ijọba lẹkajẹka lati gbe oniruuru eto ti yoo fi ifẹ han si awọn ti ko rọwọ họri lawujọ, ti yoo si fun wọn ni ireti kalẹ.
Ọba Akanbi fi kun ọrọ rẹ pe awọn ọmọ Naijiria ko fi ifẹ han si awọn alaini rara, eyi ti ko si yẹ ko ri bẹẹ, idi si niyẹn toun fi n gbe igbesẹ lati mu inu wọn dun.
O ni ‘Iya n jẹ awọn ọmọ orileede Naijiria. Gẹgẹ bii ọba, n ko le sọ pe mo ni ẹgbẹrun lọna ogun Naira lọwọ. Ti mo ba jẹ banki lowo, ele yoo maa gun un lojoojumọ, ṣugbọn wọn ko owo mi sọdọ bayii, ko si si ele to gun ori ẹ.
”Mi o ro pe Naijiria n dagbasoke rara. Ko ṣee ṣe lati paarọ owo, ka si tun ko owo kuro niluu nigba kan naa, ko bojumu rara. Ṣe a ni awọn adari pẹlu nnkan to n ṣẹlẹ yii?
“N ko ro pe o yẹ ki Emefiele ṣi wa nibẹ. Iya n jẹ awọn ọmọ Naijiria, wọn ko lanfaani si owo wọn. Iwa buruku gbaa ni, o yẹ ki wọn tun inu wọn ro.