Adewale Adeoye
Titi di akoko taa n koroyin yii jọ, awọn agbebọn kan ti wọn waa ji Imaamu agba mọṣalaṣi nla kan atawọn ẹbi rẹ pẹlu awọn tọkọ-taya ti wọn ṣẹṣẹ ṣegbeyawo laipẹ yii lagbegbe kan ti wọn n pe ni Millennium City, nipinlẹ Kaduna, ko ti i pe mọlẹbi wọn lati sọ ohun ti wọn fẹẹ gba lọwọ ẹbi awọn ẹni ti wọn ji gbe yii. Bakan naa lawọn alaṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa ti sọ pe awọn maa too bẹrẹ si i wọnu igbo nla kan ti wọn ni ibẹ lawọn agbegbọn ọhun ko gbogbo awọn ti wọn ji gbe sa gba.
ALAROYE gbọ pe ni aṣaalẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun yii, lẹyin tawọn araalu naa kirun aṣaalẹ tan lawọn agbebọn ọhun tawọn kan sọ pe o ṣee ṣe ko jẹ ajinigbe ya wọ agbegbe ‘New Millennium City’, to wa nijọba ibilẹ Chikun, nipinlẹ Kaduna, ti wọn si ji awọn araalu mẹjọ gbe sa lọ rau.
Lara awọn ti wọn ji gbe ọhun ni Imaamu agba mọṣalaṣi nla kan to wa ninu ilu naa, iyawo rẹ ati ọmọ oṣu mẹta kan to n tọ lọwọ pelu awọn ọmọ mẹta miiran ti wọn jẹ ọmọ Imaamu ọhun. Bakan naa ni wọn tun ji awọn tọkọ-taya kan ti wọn ṣẹṣẹ ṣegbeyawo alarinrin laipẹ yii gbe sa lọ.
Ọkan lara awọn olugbe agbegbe yii ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ ṣalaye pe ni nnkan bii aago mẹsan-an ku iṣẹju mẹwaa alẹ ọjọ Tusidee, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ni awọn agbebọn ọhun tiye wọn jẹ mẹwaa ya wọnu ilu naa pẹlu ibọn AK-47 lọwọ wọn. Bi wọn ṣe wọnu ilu naa ni wọn n yinbọn soke gbau-gbau lati da ipaya nla silẹ lọkan awọn eeyan. Taarata ni wọn lọ sile Imaamu agba mọṣalaṣi nla ọhun, ti wọn si ji i gbe sa lọ pẹlu gbogbo ẹbi rẹ pata, lẹyin naa ni wọn ṣẹṣẹ tun lọ sawọn ile to sun mọ ile Imaamu naa, ti wọn si tun ji awọn tọkọ-taya kan ti wọn ṣẹṣẹ ṣegbeyawo lọ.
O tẹsiwaju si i pe, ‘‘Emi paapaa wa ninu ile lakooko tawọn agbebọn ọhun wa sile wa, ti wọn si ji awọn tọkọ-taya ọhun gbe, ẹnu ọna ile rẹ ni wọn kọkọ duro si ti wọn si n gbalẹkun ile rẹ pẹlu agbara, wọn gba a titi, bẹẹ ni wọn n pariwo pe ko ṣilẹkun fawọn, idi emi paapaa ti domi sibi ti mo wa, nigba ti wọn ko ri ilẹkun ile ọhun ja ni wọn ba fọ oju windo rẹ wọle, wọn ṣe ọkọ ọhun leṣe gidi, ti ẹjẹ si n kan lara rẹ bi wọn ṣe n fipa mu oun pẹlu iyawo rẹ lọ. Wọn iba ji emi paapaa gbe sa lọ, nibi ti wọn ti n ba irin to wa loju windo mi ja lọwọ ni ọkan lara awọn ọdẹ adugbo wa ti yinbọn soke gbau, iro ibọn ọhun ti wọn gbọ ni ko jẹ ki wọn pari iṣẹ ọwọ wọn lọdọ mi, ẹru ba wọn gidi, wọn si sa lọ nitori ti wọn ko mọ boya awọn ọlọpaa tabi ṣọja lo de saduugbo naa’.