Ọlawale Ajao, Ibadan
Inu ibanujẹ lọpọ awọn akẹkọọ atawọn alaṣẹ fasiti aladaani kan, Ajayi Crowther University (ACU), to wa niluu Ọyọ, wa bayii pẹlu bi wọn ṣe fipa ba ọkan ninu awọn akẹkọọ-binrin fasiti naa laṣepọ.
Ohun to tubọ mu ki iṣẹlẹ yii bi wọn ninu ni pe awọn ọdẹ ti wọn fi ọwọ ara wọn gba, ti wọn si n sanwo fun, gan-an ni wọn huwa ọdaran naa.
Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, lasiko t’ọmọbinrin naa n gba atẹgun kiri lalẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹsan-an, oṣu Karun-un, ọdun 2024 yii, lo ko sọwọ meji ninu awọn fijilante to n ṣọ ileewe naa, ti awọn mejeeji si ki i mọlẹ, ti wọn fipa ba a laṣepọ.
Bi ọmọbinrin ti wọn forukọ bo laṣiiri yii ṣe fi iṣẹlẹ ọhun to awọn alaṣẹ ileewe naa leti ni wọn ti mu awọn to huwa ọdaran naa, loju-ẹsẹ ni wọn si ti bẹrẹ igbesẹ lati ri i pe wọn jiya to tọ si wọn labẹ ofin.
Awọn akẹkọọ paapaa ko fọwọ yẹpẹrẹ mu ọrọ yii pẹlu bi wọn ṣe fẹhonu han, wọn ni iya yii ko gbọdọ jẹ akẹgbẹ awọn gbe, awọn afurasi ọdaran naa gbọdọ jiya ẹṣẹ wọn ni dandan.
Awọn alaṣẹ fasiti yii paapaa ko fi ojuure wo iṣẹlẹ yii atawọn to huwa ọdaran ọhun, wọn ti mu awọn afurasi ọdaran naa, wọn si ti fa awọn mejeeji le ọlọpaa lọwọ.
Ninu atẹjade ti Ọgbẹni Fẹmi Atoyebi, ti i ṣe alukoro ileewe ọhun fi ṣọwọ sawọn oniroyin, o ni, “Ni nnkan bii aago kan oru lonii (ọjọ Jimọ, ọjọ kẹwaa, oṣu yii), lọga agba ileewe yii, Ọjọgbọn Timothy Abiọdun Adebayọ, ṣepade pẹlu awọn eekan nileewe ọhun lori iṣẹlẹ yẹn. Awọn bii Ọmọwe Roand Isibor, ti i ṣe alamoojuto ọrọ to ni i ṣe pẹlu awọn akẹkọọ; Ọjọgbọn Ayọdabọ, alaga igbimọ to n ri si ọrọ eto aabo lọgba yii; Aarẹ ẹgbẹ awọn akẹkọọ, Ibukunoluwa Taiwo, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
“Wọn ti mu awọn afuasi ọdaran naa, wọn si ti fa wọn le awọn ọlọpaa lọwọ fun ijiya to ba tọ si wọn labẹ ofin.
“A o ni i faaye gba ki wọn bo ẹjọ yẹn mọlẹ rara. Awọn alaṣẹ ileewe yii paapaa ti gbe igbimọ kan dide fun iwadii ati itọpinpin iṣẹlẹ yii”.