Wahala! Wahala! Awọn ọlọpaa ya lọ sile igbafẹ Portable olorin Zazuh

 Jọkẹ Amọri

 Asiko yii ki i ṣe eyi to dara rara fun ọmọkunrin olorin taka-sufee nni, Habeeb Okikiọla Ọlalọmi, ti gbogbo eeyan mọ si Portable tabi Zah Zuh olorin. Beeyan ba ri ọkunrin naa bo ṣe n lọgun tantan, to n mi soke sodo, to si n laagun yọbọ bii ẹni to ṣẹṣẹ jade ninu ileeṣẹ burẹdi, ninu fidio kan to gba ori ayelujara, tọhun yoo mọ pe nnkan ko sẹnuure fun ọmọkunrin naa.

Ohun to fa gbogbo ariwo ti Portable to maa n saaba pariwo, ‘wahala wahala’’ yii ni bi awọn ọlọpaa kan ṣe gbe mọto wa si ile igbafẹ rẹ to wa ni Oke-Ọsa, niluu Ọta, nipinlẹ Ogun, ti wọn fẹẹ ko awọn ọmọọṣẹ rẹ atawọn to waa ṣe faaji nibẹ.

Niṣe ni ọmọkunrin naa bẹrẹ si i pariwo, to n lọgun gidi, to si n beere ohun ti awọn ọlọpaa waa ṣe nile-igbafẹ rẹ.

Nigba ti awọn agbofinro naa sọ pe awọn kan ni wọn kọ iwe ẹsun wa, Portable ni afi ki wọn sọ ohun ti oun ṣe ati ohun to wa ninu iwe ẹsun naa. Bẹẹ lo fi aidunnu rẹ han si bi wọn ṣe waa da ile igbafẹ naa ru, ti gbogbo awọn to wa nibẹ si n sa kijo kiji.

Portable ni, ‘Ki lẹ n wa nile igbafẹ mi, kin ni mo ṣe fun yin. Ki lo de ti ọkunrin yẹn fi ni awọn fẹẹ waa mu mi, ki lo de ti ẹ n sọ pe ẹ fẹẹ waa mu emi ilu mọ-ọn-ka akọrin ni ọfiisi mi’. Nigba ti ọkan ninu awọn agbofinro naa sọ pe iwe ẹsun nipa rẹ lo wa si ileeṣẹ ọlọpaa lo sọ pe ‘‘Ṣe nitori iwe ẹsun lẹ ṣe ko ọlọpaa ati ibọn waa ba mi, ti ẹ le gbogbo awọn kọsitọma mi lọ, ti gbogbo eeyan n sa kitikiti kiri, bi ki i baa ṣe pe emi naa laya, mi o ba sa lọ. Ki ni mo ṣe, ki lo wa ninu iwe ẹsun, ki ni wọn ni mo ṣe, ẹ jẹ ki n ri iwe idanimọ yin.

 ‘‘Ki lo de ti ẹ ko fiwe pe mi pe ki n wa si ọfiisi yin, mo le wa, mo si le ran manija mi wa, emi naa ni manija, ilu mọ-ọn-ka lemi naa, ọmọ ijọba ni mi, awa la ni Naijiria bayii, awa la n paṣẹ ni Naijiria bayii, awa la wa nipo ijọba bayii, nitori APC ni mo ṣiṣẹ fun, kin ni mo ṣe fun yin, ki lo ṣẹlẹ, ki lẹ fẹẹ ṣe pẹlu mi, mi o ni i gba. Ẹ ti wọle tọ were, ẹ maa ri wahala o. Awọn kan ni wọn ni ki ẹ waa da ile igbafẹ mi ru…

‘‘Wọn le mi titi lati Lekki, mo sa wa sinu igbo, mo n gbe inu igbo bii ọbọ, ẹ tun le mi wa sinu igbo, inu igbo ni mo n gbe…’’

Awọn ọrọ bayii ati ọpọlọpọ bẹẹ lọmọkunrin olorin taka-sufee naa n sọ, bẹẹ lo n lọgun, to n laagun, to si n pariwo le awọn ọlọpaa naa lori ninu fidio to n ja ranyin lori ayeluara naa.

 

Leave a Reply