Ọlawale Ajao, Ibadan
Agba ọjẹ lagbo ere Fuji, Alhaji Wasiu Salawudeen Gbọlagade Ayinde, ti jade láyé.
Losan-an Ọjọbọ, Tọsidee, lọkunrin to fi orin kikọ jọ Wasiu Ayinde (K1 Dé Ultimate) yii jade laye.
Lẹyin to kirun ọsan tan ni wọn lo deede ṣubú lulẹ̀, ti ọkunrin ti ko ṣàìsàn tẹlẹ yii sì di ẹni tí wọn sáré gbe digba-digba lọ sileewosan fún itọju
Ṣugbọn nigba ti wọn yóò fi dọ́sibítù, ẹ́lẹ́ran ti túkùn lọrun akọni.
Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, gbajumọ olorin Fuji ti awọn èèyàn tun mọ si Wasiu Afárá yii fi orin atata da awọn éèyàn laraya nibi ariya kan ti wọn ṣe l’Ogbomọṣọ ti í ṣe ilu abinibi ẹ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ìyẹn lọjọ to ku ọlá to maa ku gan-an, lai mọ pe àkọgbẹ̀yìn orin oun loun kọ lọjọ naa.
Oun lolorin Fuji to lamilaaka ju lọ niluu Ogbomọṣọ. Ta a ba sí yọwọ Alhaji Rasheed Ayinde Merenge ati Alhaji Taye Adebisi Currency ti wọn n gbe ilu Ibadan kuro, boya lolorin Fuji kan wa nipinlẹ Ọjọ to làlùyọ to ọkunrin to doloogbe yii. Bi eeyan ko ba sì jẹ ẹni to ti n gbọ orin awọn mejeeji tipẹ́, o ṣòro ki oluwa ẹ̀ tóo lè mọ pe ki í ṣe Wasiu Ayinde Ọba Fuji lo n pèdè nigbakugba ti Alhaji Wasiu Ayinde Ogbomọṣọ yii ba n kọrin.
Itẹkuu awọn Musulumi to wa niluu Ogbomọṣọ ni wọn sinkú olorin Fuji naa si nirọlẹ Ọjọ́bọ̀, Tọsidee, kan naa to dagbere faye.