Adewale Adeoye
Titi di akoko ta a n koroyin yii jọ, ko ti i sẹni to mọ koko ohun ti ipade idakọnkọ kan to waye laarin olori orileede yii, Aarẹ Bola Ahmed Tinubu ati gomina ipinlẹ Rivers tẹlẹ, Ọgbẹni Nysom Wike, Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ṣeyi Makinde ati Oloye James Ibori, eyi to waye ninu ọfiisi Aarẹ to wa ni Aso Rock, niluu Abuja da le lori. Ohun tawọn kan to sun mọ awọn eeyan naa daadaa n sọ ni pe ipade pajawiri naa ni i ṣe pẹlu ọrọ oṣelu ilẹ wa, ati pe o ṣee ṣe ki wọn tun fẹẹ gba ipo pataki ninu ijọba Tinubu, nitori pe ko fara sin rara pe awọn eeyan naa kopa pataki lakooko ti ọkunrin yii n dupo aarẹ orileede yii, bo tilẹ je pe ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ni wọn.
ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii ago meji aabọ ọsan ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ keji, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii, lawọn mẹtẹẹta de siluu Abuja, bi wọn si ti ṣe de sile ijọba ni Aso Rock, ni wọn ti lọ taarata sibi ti Aarẹ Tinubu ti n duro de wọn fun ipade pataki naa.
Wọn ko gba awọn oniroyin kankan laaye lati ba awọn eeyan naa wọnu ibi ti wọn ti fẹẹ ṣepade pataki ọhun pẹlu Aarẹ, eyi lo si fa a ti ko fi sẹni to mọ koko ohun ti ipade idakọnkọ naa da lori laarin awọn eeyan naa.
Bẹẹ o ba gbagbe, ki Wike too fipo silẹ gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Rivers lo ti ranṣẹ pe Tinubu pe ko waa b’oun ṣi awọn iṣẹ akanṣe pataki kan ti ijọba rẹ ṣe fawọn araalu nipinlẹ rẹ. Igbesẹ yii lo mu ki ọpọ maa sọ pe, o ṣee ṣe ko jẹ pe Wike paapaa ko ni i pẹẹ kede pe oun ti darapọ mọ ẹgbẹ APC bayii.
Bakan naa lawọn kọọkan n sọ pe atilẹyin nla ti Wike ati Gomina Makinde ṣe fun Aarẹ Tinubu wa lara ohun to gbe e depo ọhun, nitori pe ki i ṣe ibo kekere rara lawọn mejeeji fun Tinubu nipinlẹ wọn lakooko ibo to waye lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keji, ọdun 2023 yii.