Jọkẹ Amori
Iyalẹnu nla lo jẹ fun gbogbo awọn to wa nibi ti Gomina ipinlẹ Rivers, Nyesome Wike, ti kede ‘atilẹyin’ rẹ fun oludije funpo aarẹ lẹgbẹ oṣelu Labour Party, Peter Obi. Ọkunrin naa ni gbogbo amuyẹ to yẹ ki ẹni to ba fẹẹ dupo aarẹ ni lo wa lara ọmọ bibi ipinlẹ Anambra naa, oun si ti ṣetan lati ṣe ‘atilẹyin’ fun un nipa pipese awọn ohun to maa nilo fun ipolongo idibo rẹ nigbakugba to ba wa si ipinlẹ naa.
Ohun to jẹ ki eyi jẹ iyanu ni pe awọn eeyan naa ki i ṣe, ọmọ ẹgbẹ oṣelu kan naa. PDP ni Wike wa, Labour Party ni Obi wa.
Wike sọrọ yii lasiko to n ṣi afara kan Nkpolu-Oroworukwo ni ipinlẹ naa, to si pe Obi gẹgẹ bii ọkan ninu awọn alejo pataki sibẹ lati ṣi i. O ni nigbakugba ti Peter Obi ba ti wa si ipinlẹ Rivers lati ṣe ipolongo ibo rẹ, gbogbo ohun to ba nilo patapata loun yoo pese fun un.
Wike ni, ‘‘Igbakugba to o ba fẹẹ polongo ibo rẹ nipinlẹ Rivers, jẹ ki n mọ, gbogbo ohun to o ba nilo fun ipolongo naa la maa pese fun ọ.
‘‘Mo mọ ọ gẹgẹ bii ẹni kan, mo mọ pe gbogbo amuyẹ ati awọn iwa teeyan to to ba fẹẹ ṣe aarẹ Naijiria gbọdọ ni lo wa lara rẹ’’.
Bakan naa lo sọko ọrọ si Gomina ipinlẹ Anambra, Ọjọgbọn Soludo, pẹlu awọn ọrọ abuku to sọ nipa Obi laipẹ yii. Ọkunrin naa ni ko fi Obi silẹ, ko gbaju mọ iṣejọba tiẹ, ko yee sọrọ nipa iṣejọba to ti lọ, tabi ko maa bu ẹnu ẹtẹ lu ijọba naa.
Ki oun naa ṣe tiẹ ki gbogbo aye ri i.
O fi kun un pe idi pataki ti oun fi pe Obi ko waa ṣe ifilọlẹ afara naa ni pe o pe ara rẹ ni onisowo. Gomina yii ni nigba ti oun fẹẹ bẹrẹ afara naa, oriṣiiriṣii ibanilorukọ jẹ lo waye, ti awọn kan si n sọ pe oun fẹẹ le awọn Ibo lọ ni, wọn ko mọ pe ko si bi eeyan ṣe le ṣowo ko gbadun rẹ bi ko ba si ohun amayedẹrun ati agbegbe to daa. Sugbọn gbogbo wọn ni wọn mọ riri ohun ti oun ṣe yii.
Wike lu Obi lọgọ ẹnu, o ṣapejuwe rẹ bii onirẹlẹ, ẹni to ṣee gbẹri rẹ jẹ, o ni oun mọ pe idukooko ati ifiyajẹni lo mu ko kuro ninu ẹgbẹ PDP. Gomina naa ni oun ko ni i fi ẹgbẹ oṣelu PDP silẹ fun awọn adigunjale lati gba a, inu ẹgbẹ naa ni oun maa duro si ti oun maa fi le wọn lọ.