Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti
Ṣọja kan ti ileeṣẹ ologun ilẹ wa ko darukọ rẹ ti yinbọn pa ọga ẹ ni Bama, nipinlẹ Borno.
Gẹgẹ bi Ọgagun Sagir Musa to jẹ alukoro ileeṣẹ ologun ṣe sọ, ni nnkan bii aago mẹwaa aabọ alẹ Ọjọruu, Weṣidee, ana, niṣẹlẹ naa waye.
Musa ṣalaye pe lasiko ti oloogbe naa n gbe ipe lori foonu rẹ ni ṣọja to wa ni ọ̀wọ́ 202 Battalion ọhun lọọ ba a, to si deede yinbọn pa a.
O ni ọwọ ti tẹ afurasi naa, oloogbe si ti wa ni mọṣuari, bẹẹ ni wọn ti tufọ fun awọn mọlẹbi ẹ.
Alukoro naa ni iwadii n lọ lọwọ lati mọ idi tiṣẹlẹ naa fi waye, bo tilẹ jẹ pe awọn kan gbagbọ pe ailera ọpọlọ ṣọja naa lo fa igbesẹ to gbe.