Wolii ijọ kan ti wọn n pe ni Evangelical Spiritual Church (INRI), Primate Elijah Ayọdele, ti kilọ fun Atiku to n sọ pe ki wọn fi orukọ Ọbasanjọ sori owo ilẹ wa pe ki wọn ma dan an wo rara, o ni ohun to lewu gidigidi ni. Ọkunrin naa ni ohun ti wọn n beere fun yii, ajalu buruku ati ifasẹyin ni yoo mu ba ọrọ-aje ilẹ wa bi wọn ba le fi aworan Ọbasanjọ sori owo ilẹ wa.
Ninu ijọ rẹ lo ti sọrọ yii lasiko to n waasu lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, gẹgẹ bin iweeroyin PM news ṣe sọ.
Ọkunrin ariran naa ni ki ijọba apapọ ma ṣe da Atiku lohun pẹlu bo ṣe n sọ pe ki wọn fi fọto ati orukọ Ọbasanjọ sori owo ilẹ wa gẹge bi wọn ṣe da Emefiele loun nigba to ni oun yoo paarọ awọ owo ilẹ wa. O ni owo wa yoo bajẹ ju bo ṣe wa yii lọ, inira ati wahala yoo pọ si i ju bi wọn ba le fi orukọ Ọbasanjọ ati aworan rẹ sara owo ilẹ wa.
Ọkunrin arina yii bu ẹnu atẹ lu Atiku, o ni nitori oṣelu, ati ki Ọbasanjọ le fẹran rẹ lo fi mu aba yii wa, ṣugbọn pẹlu rẹ, o ni Ọbasanjọ ko le tori ohun to sọ yii fẹran rẹ.
Ayọdele ni, ‘‘Ki lo de ti o n ṣe apọnle Ọbasanjọ, iparun nla ni o n mu ba ara rẹ bi o ṣe n ṣe apọnle rẹ, ko si le tori eyi fẹran rẹ. Ki Buhari ma ṣe gba amọran Atiku lati fi orukọ Ọbassanjọ sori owo wa, nitori ni kete ti aworan Ọbasanjọ ba debi owo wa ni ọrọ-aje wa yoo bajẹ si i.
‘‘Bii ajalu ati iyọnu nla ni ki eeyan fi orukọ Ọbasanjọ sori owo ilẹ wa. Mi o mọ idi ti Atiku fi sọ iru ọrọ bẹẹ, ko yaa tete jade, ko ko ọrọ naa jẹ kiakia. Ṣe o n lo eleyii fun ipolongo ni? Ṣe Ọbasanjọ lo maa jẹ ko wọle ibo ni, ṣe Ọbasanjọ maa jẹ ko yege lasiko ibo ni? Ṣe eleyii yoo yi ero ọkan Ọbasanjọ nipa rẹ pada ni? Eyi ko le ṣẹlẹ rara, imọran to lodi gbaa ni.
‘‘Ọrọ ti Atiku sọ yii ko weti i gbọ, ko daa, ko si bọ si asiko to daa, nitori ni kete ti orukọ Ọbasanjọ ba wọ ara owo ilẹ wa, inira ati gbese ti ko ni i ṣee san tan ni yoo ba ọrọ aje ilẹ wa, owo Naira yoo si bajẹ patapata. Atiku ko mọ ohun to n sọ lori eleyii, ko si daa ko maa fi ọrọ-aje ilẹ wa ṣe oṣelu’’.
O waa rọ Buhari lati ma tẹti si Atiku gẹgẹ bo ṣe tẹti si Olori Banki ilẹ wa, Godwin Emefiele, lori titun awọn owo ilẹ wa ṣe. O ni eyi ki i ṣe ọna abayọ, bẹẹ ni ko le mu ohunkohun jade. Wolii yii ni Ọlọrun lo yẹ ka gbadura si ko ṣe agbedide ọrọ aje wa.
Tẹ o ba gbagbe, laipẹ yii ni oludije funpo aarẹ lorukọ ẹgbẹ PDP, Atiku Abubakar, jade pe o yẹ ki wọn fi oye da aarẹ ilẹ wa tẹlẹ, Oluṣẹgun Ọbasanjọ, lọla, ki wọn si fi orukọ rẹ sara owo ilẹ wa, nitori awọn ilaja ọlọjọ pipẹ ti ẹnikẹni ko ro pe o le ṣee ṣe mọ to waye ni awọn orileede Afrika kan, ṣugbọn ti Ọbasanjọ yanju re, ti alaafia si bẹrẹ si i jọba laarin awọn ti wọn n ja.
Ni bii ọsẹ meji sẹyin ni olori banki apapọ ilẹ wa(CBN), Godwin Emefiele, kede pe awọn fẹ ki owo ilẹ wa gbe awọ tuntun wọ, lara idi to fi ni eleyii ṣe pataki ni pe awọn owo to wa nita ti dọti. Ọpọ awuyewuye lo ti n waye lori eleyii, ṣugbọn Aarẹ Buhari jade lẹyin ọjọ diẹ ti wọn ti n fa ọrọ naa pe oun ṣe atilẹyin fun igbesẹ naa.
Ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kejila, ni wọn ni owo Naira tuntun yii yoo jade sita.