Ọlawale Ajao, Ibadan
Ojiṣẹ Ọlọrun kan, Wolii Modes Aladeolu, ti gba awọn to n dupo gomina ipinlẹ Ọyọ ta ko Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde ti i ṣe gomina ipinlẹ naa nimọran lati jawọ ninu erongba naa, ki wọn ma baa fowo ara wọn jona.
Wolii Aladeolu, to jẹ Oludasilẹ ijọ Christ Apostolic Church, CAC, to wa laduugbo Ọjọọ, lọna Moniya, n’Ibadan, sọ pe Ọlọrun ti fi han oun pe Makinde ni yoo wọle fun saa keji nipo gomina, gbogbo awọn to n ba a dupo ọhun yoo kan fowo wọn ṣofo lasan ni.
Ninu atẹjade to fi ṣọwọ sọfiisi ALAROYE n’Ibadan, eyi to pe akori ẹ ni “Ifihan Oluwa Si Wa ni Ipinlẹ Ọyọ’’, wolii yii sọ pe “Ọlọrun Ọba ajọkẹ aye, aṣakẹ ọrun, Ọlọrun to ni aye ati ọrun, lo ran mi si ẹyin ọba, ijoye, alagbara nipa ti ara ati ninu ẹmi, paapaa ẹyin oloṣelu nipinlẹ Ọyọ pe ki gbogbo wa fọwọsowọpọ lati fun Ọlọla wa, Ẹnjinnia Oluwaṣeyi Abiọdun ọmọ Makinde lanfani lati ṣakoso ijọba yii lẹẹkan si i.
“Gbogbo ẹyin olowo, tẹ ẹ lowo lati ṣe ohun to wu yin, mo bẹ yin, ẹ ma ṣe na owo yin lati du ipo gomina ipinlẹ Ọyọ.
“Mo mọ pe ẹ gbọn, ẹ si lagbara, ṣugbọn Ọlọrun to pe mi gẹgẹ bii iransẹ Rẹ lo ran mi pe: o tun ku ti Oun fẹẹ lo Ẹnjinnia Oluwaṣeyi Abiọdun Makinde fun. Ẹ jọwọ, ẹ jẹ ka fun Ọlọrun laaye ki O tun lo o lẹẹkan si i”.
O ni yatọ si pe Ọlọrun fi han oun pe Makinde ni yoo wọle fun saa keji nipo gomina, awọn aṣeyọri ẹ ni saa akọkọ to n lo lọwọ lori apere ijọba yii ko ṣee fẹnu sọ.
Wolii tawọn eeyan tun mọ si Baba Ori-Oke yii fi kun un pe eyi to wu oun lori gẹgẹ bii ẹlẹran ara ninu awọn aṣeyọri gomina yii ni iṣẹ to pese fawọn ọdọ, ati bi ko ṣe jẹ ki awọn oluwaṣẹ ṣẹṣẹ maa fowo gba fọọmu ko too gba wọn siṣẹ.
Nigba to n rọ awọn to n ba Ẹnjinnia Makinde dupo gomina ninu idibo ọdun to n bọ lati tun ero wọn pa, Wolii Aladeolu fi kun un pe “bi Ọlọrun ti ran mi naa ni mo ṣe bẹ yin lati fun Ẹnjinnia Makinde laaye lati jiṣẹ ti Ọlọrun Ọga ogo ran an fun ipinlẹ Ọyọ.
“Ẹyin tẹ ẹ fẹẹ dupo nla yii, mo bẹ yin, ẹ ṣe suuru di igba mi-in, iku aitọjọ ko ni i pa yin, aisan ko ni i de yin mọlẹ, ẹ jọwọ, ẹ gba fun Ọlọrun”.
Bakan naa lo gba awọn oludibo nimọran lati ma ṣe gbowo lọwọ awọn oloṣelu to ba fi owo lọ wọn lasiko idibo, nitori iru iwa bẹẹ maa n sọ awọn araalu di ẹru awọn oloṣelu ni.