Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ṣe ẹ ranti Wolii Salami Kayọde ti ọmọ ijọ rẹ ku sinu ṣoọṣi rẹ, ti aṣiri si pada tu pe niṣe lo fẹẹ fipa ba obinrin ti ọkọ rẹ wa niluu oyinbo, to si ti bimọ kan naa lo pọ. Lasiko ti wọn jọ n bara wọn fa wahala lori eleyii ni obinrin naa dakẹ mọ ọn labẹ. Wọn ti foju rẹ ba ile-ẹjọ Majisireeti kẹta to wa l’Oke-Ẹda, niluu Akurẹ, ṣugbọn ọkunrin naa loun ko jẹbi pẹlu alaye.
Wolii ẹni ọgbọn ọdun ọhun ni wọn fẹsun kan pe o fun obinrin ọmọ ọdun marundinlogoji naa lọrun, eyi to pada ja siku fun un.
Iṣẹlẹ ọhun ni wọn lo waye ninu ijọ Kerubu ati Ṣerafu to wa lagbegbe Oke-Irapada, ni Alade-Idanre, nijọba ibilẹ Idanre, ni nnkan bii aago mẹfa ku iṣẹju mẹẹẹdọgun, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹta, ọdun 2023 yii.
Agbefọba, Abdulateef Suleiman, sọ ni kootu pe ẹsun ti wọn fi kan olujẹjọ ta ko abala okoolelọọọdunrun din mẹrin (316) ninu iwe ofin ipinlẹ Ondo ti ọdun 2006. O ni oun fẹ ki kootu paṣẹ fifi olujẹjọ naa pamọ sọgba ẹwọn titi ti awọn yoo fi rí imọran gba lati ọfiisi ajọ to n gba adajọ nimọran.
Nigba to n gbe ipinnu rẹ kalẹ, Onidaajọ N. T. Aladejana gba ẹbẹ agbefọba naa wọle pẹlu bo ṣe ni ki wọn ṣi maa mu Wolii Salami lọ si ọgba ẹwọn Olokuta, titi di ọgbọnjọ, oṣu Karun-un, ọdun 2023, ti igbẹjọ yoo tun maa tẹsiwaju.
Tẹ o ba gbagbe, o to bii oṣu meji ti ọmọbinrin naa ti n sun, to n ji, ninu ṣọọsi wolii ijọ alaṣọ funfun yii naa ki iya rẹ too pada mọ pe ibẹ lo ku to fi ṣe ibugbe lẹyin to sa kuro lọdọ oun.
Lara ohun to mu ki wọn fura si Wolii Salami lori iṣẹlẹ ta a n sọrọ rẹ yii ni ti sokoto to wọ lasiko naa, eyi to ja labẹ, ati ẹjẹ ti wọn ri to n jade lati oju ọgbẹ kekere kan to wa ni igi-imu rẹ, eyi tawọn eeyan fi n sọ pe o ṣee ṣe ko jẹ pe oun ati oloogbe naa wọdimu, lasiko naa niyẹn si da ọgbẹ naa si i lara.
Alaye ti Wolii Salami ṣe nigba ti ALAROYE kọkọ fọrọ wa a lẹnu wo ni pe ṣọọbu oun, nibi toun ti n ṣiṣẹ wẹda loun wa nigba ti oun gbọ nipa iku ọmọbìnrin naa.
Wolii ẹni ọdun mẹtadinlogoji ọhun ni kayeefi patapata lọrọ iku obinrin naa ṣi n jẹ foun, nitori lójijì loun gbọ ariwo iya rẹ lasiko ti oun wa ninu ṣọọbu oun, eyi ti ko fi bẹẹ jinna si ṣọọsi.
Nigba ti akọroyin wa beere bi ọrọ sokoto rẹ to ja labẹ ati ẹjẹ to wa nigiimu rẹ ṣe jẹ, àti idi to fi jẹ iru sokoto yii lo wọ lọjọ naa, esi to fun wa ni pe ṣe loun mọ-ọn wọ sokoto ọhun nitori o ṣee ṣe ki oun ma lanfaani ati lo o mọ lẹyin ọjọ naa.
Nipa ti ẹjẹ to tun wa nigiimu rẹ, o ni ẹnikan lo gba oun lẹṣẹẹ nimu, nibi ti oun ti n laja laarin tọkọ-taya kan lọsan-an ọjọ naa gan-an.