Wọn ṣa adari ẹgbẹ PDP pa siwaju ile baba ẹ l’Ọyọọ

Ọlawale Ajao, Ibadan

Oṣelu ipinlẹ Ọyọ ba ọna mi-in yọ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kejila, ọdun yii, pẹlu bi awọn afurasi janduku oloṣelu kan ṣe ṣigun lọọ ka ọmọ ẹgbẹ People’s Democratic Party (PDP) kan, Mudashiru Baraka, mọle, ti wọn si ṣa a ladaa pa.

Bi gbogbo ilu Ọyọ ṣe tobi to, Baraka, to jẹ ogunna gbongbo ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ni wọn lo maa n ba wọn ko ero jọ nigba yoowu ti ẹgbẹ Alaburada ba nilo awọn ọmọ ẹgbẹ to pọ ninu ilu naa tabi bi wọn ba fẹẹ ko wọn lọ sẹyin odi fun eto tabi ipolongo.

Laaarọ ọjọ Wẹsidee yii la gbọ pe awọn ọmọ iṣọta ọhun ti wọn dihamọra pẹlu ada, igo atawọn nnkan ija oloro loriṣiiriṣii ya lọọ ka Baraka mọ inu agboole wọn, ti wọn si ṣa a ladaa pa a siwaju ita ile baba ẹ nibẹ.

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ yii lori ikanni ibanidọrẹẹ rẹ lori ẹrọ ayelujara, Alukoro fẹgbẹ oṣelu Alaburada nipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Akeem Ọlatunji, fìdi ẹ mulẹ pe awọn tọọgi inu ẹgbẹ oṣelu alatako lo gbẹmi ọdọmọkunrin oloṣelu naa. O fi kun un pe awọn ti fi iṣẹlẹ naa to awọn agbofinro leti ni teṣan ọlọpaa to wa ni Durbar, niluu Ọyọ.

A ko ti i lanfaani lati fidi iṣẹlẹ yii mulẹ lọdọ awọn agbofinro titi ta a fi pari akojọ iroyin yii.

Ṣugbọn Alukoro fẹgbẹ oṣelu PDP ti  rọ ọga agba awọn ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, CP Adebọwale Williams, lati ṣewadii iṣẹlẹ yii, ki wọn si fi imu awọn ọdaran naa danrin.

 

Leave a Reply