Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Awọn arinrinajo mejilelọgbọn lawọn agbebọn kan tun ji gbe lagbegbe Ifọn lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹta, oṣu yii.
Awọn arinrin-ajo ọhun ti wọn wa ninu ọkọ bọọsi Kosita kan la gbọ pe wọn ji gbe loju ọna marosẹ Ifọn si Benin, lasiko ti wọn n pada bọ lati ibi ayẹyẹ isinku ti wọn lọọ ba ẹnikan ṣe niluu Benin, nipinlẹ Edo.
Nigba to n fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ, adari ẹṣọ Amọtẹkun nipinlẹ Ondo, Oloye Adetunji Adelẹyẹ, ni loju-ẹsẹ tawọn gbọ nipa iṣẹlẹ ọhun lawọn oṣiṣẹ awọn ti fọn sinu igbo lati lepa awọn ọdaran ajinigbe naa.
Oludamọran gomina lori eto aabo ọhun ni gbogbo igbesẹ lawọn n gbe lọwọ lati ri awọn ti wọn ji gbe naa gba pada lọwọ awọn agbebọn ọhun laaye.
Alukoro ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Funmilayọ Ọdunlami, sọ ninu ọrọ tiẹ pe eeyan mọkanla pere ni wọn jì gbe ninu ọkọ kosita ọhun lagbegbe Omi-Alaga, loju ọna marosẹ Ifọn si Ọwọ ti iṣẹlẹ yìí ti waye.
Ó ni ọkan ninu awọn ero ọkọ naa ti ori ko yọ ti n ran awọn ọlọpaa lọwọ ninu iwadii awọn.
Ọdunlami ni awọn ọlọpaa atawọn sọja ti lọ si agbegbe ti iṣẹlẹ ijinigbe ọhun ti waye lati doola ẹmi awọn ero ọkọ naa.