Faith Adebọla
Awọn janduku agbebọn ti wọn n da awọn ara Oke-Ọya laamu tun ti sọko ibanujẹ wọn, lọtẹ yii, mẹjọ lara awọn ọmọ ijọ Ridiimu to wa ni Kaduna ni wọn ji gbe lalẹ ọjọ Ẹti, Furaidee yii, wọn ti ko wọn wọgbo lọ.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, nnkan bii aago meje alẹ niṣẹlẹ naa waye, bọọsi kan lawọn eeyan naa wọ, wọn n rin irinajo lati lọọ ṣe ipalẹmọ eto isin ọdun Ajinde to n bọ lọna, lawọn agbebọn naa fi rẹbuu ọkọ wọn loju ọna marosẹ Kachia, ti wọn si ji wọn gbe.
Wọn ni lati ṣọọṣi Redeemed Christian Church of God, to wa ni adugbo Region 30, lagbegbe Trinity Sanctuary, niluu Kaduna, ni wọn lawọn olujọsin naa ti gbera, wọn si ti rin irinajo to to kilomita mẹtalelọgọta ki wọn too bọ sọwọ awọn kọlọransi agbebọn yii.
Ẹnikan to mọ nipa iṣẹlẹ ọhun, Eje Faraday, toun naa jẹ ọmọ ijọ ọhun, lo kede iṣẹlẹ yii lori atẹ fesibuuku rẹ pẹlu aworan bọọsi funfun tawọn janduku naa ṣakọlu si.
O ni, ‘Ẹ gba wa o, mẹjọ lawọn ọmọ ṣọọṣi wa to wa ninu bọọsi ti wọn n gbe lọ siluu Kaicha, wọn fẹẹ lọọ mura silẹ fun eto ijere-ọkan ta a maa n ṣe lasiko ajọdun Ajinde ni o, awọn janduku ti da wọn lọna, wọn ja wọn bọọlẹ, wọn ko wọn sinu ọkọ tiwọn, wọn si ti wa wọn wọgbo lọ, ẹnikan o mọ’bi ti wọn wa bayii o.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kaduna, Muhammad Jalige, ti fidi iṣẹlẹ yii mulẹ. O lawọn ṣi n ṣe iwadii lati mọ hulẹhulẹ nipa ọrọ naa, awọn o si ti i gbọ ipe kan lati ọdọ awọn ajinigbe naa tabi awọn ọmọ ṣọọṣi ti wọn ji gbe.