Wọn ba eegun oku gbigbe loke aja ile Dauda atọrẹ ẹ

Faith Adebọla

Afurasi ọdaran meji kan, Dauda Rasheed, ẹni ọdun mọkanlelogoji, ati Kẹhinde Ayọade, ẹni ọdun mejilelọgbọn, ti dero ahamọ awọn ọlọpaa bayii o, eegun oku eeyan gbigbẹ ni wọn ba loke aja ile ti wọn n gbe niluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ.

Awọn ẹṣọ alaabo ijọba ibilẹ Oluyọle, iyẹn Oluyọle Security Suveillance Team, OSST, ni wọn hu u gbọ pe awọn afurasi yii ni nnkan aṣiri kan to lodi sofin labẹ orule wọn, ni wọn ba lọọ yẹ ile naa wo lọjọ Aje, Mọnde, to kọja yii, wọn si ba awọn eegun oku loriṣiiriṣii nibẹ, wọn leegun naa fihan pe obinrin lẹni ti wọn ko eegun ẹ pamọ naa maa jẹ.

Bi wọn ṣe mu wọn ni Kẹhinde ti jẹwọ ni tiẹ pe loootọ loun ati Dauda tọju awọn eegun gbigbẹ naa soke aja, tori awọn o ti i pinnu ohun tawọn maa fi i ṣe, awọn ṣi n ronu si i lọwọ ni, o labẹ igi mọngoro kan lawọn ti ri oku obinrin naa, ki i ṣe oku kan ṣoṣo lo wa nibẹ, ṣugbọn nigba to jẹra tan lawọn ṣa eegun ẹ jọ, tawọn si tọju ẹ.

Dauda, to lọmọ bibi Opopoyemọja, n’Ibadan, loun, naa jẹwọ pe awọn jọ ri oku obinrin ti wọn ko eegun ẹ ọhun labẹ igi ni, o lawọn lọọ ṣiṣẹ oko kan labule Ajanla, ni lọjọ naa, igba tawọn n pada sile lawọn fẹẹ ka eeso mọngoro, kawọn too ri oku nibẹ, ṣugbọn oun o fọwọ kan eegun oku kan ni toun o, o loun o mọgba ti Kẹhinde gbẹyin oun pada lọọ ko awọn eegun naa wale, igba to ko o de, ẹnu ya oun, n lawọn ba tọju ẹ soke aja.

Ninu alaye ti Ọga agba OSST, Kọmadanti Oluṣẹgun Idowu ṣe fakọroyin Tribune lori iṣẹlẹ yii, o ni awọn eeyan adugbo Barẹ, ni wọn ri Dauda to ti muti yo bii iru lọjọ kan, lọ ba bẹrẹ si i wi kotokoto, wọn lo n fọwọ sọya pe oun o ni i pẹẹ d’olowo yalumọ ni toun o, tori gbogbo etutu ọla oun ti fẹrẹ pe tan, oun maa dọlọla niṣeju awọn ọta oun, wọn ni bo ṣe n darin lo n gbe e.

Wọn lawọn eeyan kọkọ ro pe ọmuti gbagbe iṣẹ yii lo maa wa nidii bawọn adiẹ ati ẹran ṣe n sọnu leralera lagbegbe naa ni, ṣugbọn Dauda ko dakẹ, niṣe lo tun n fi awọn ole agbadiẹ ati aji-ṣu-wa kan tọwọ palaba wọn segi laipẹ laduugbo naa ṣe yẹyẹ, ibẹ lo si ti fẹnu kọ. Wọn lawọn ọrẹ ẹ kan ti wọn fura pe awọn lo n powe mọ, ni wọn lọọ ta ẹṣọ alaabo leti pe ṣago n bugo ẹda kan lasan lafurasi yii, wọn loun naa lẹbọ lẹru, wọn ni ki wọn lọọ tule ẹ daadaa, ibẹ si lakara ti tu sepo.

Wọn ni Kẹhinde jẹwọ pe oun o mọgba ti agbari oku tawọn tọju ṣe poora, to jẹ awọn eegun yooku lo wa nibẹ. Wọn lo tun darukọ awọn meji kan, Falafọlọ ati Apesin, o lawọn jọ ri oku ọjọ naa ni, o laṣọ ankara pupa kan lo wa lọrun oku naa, o si jọ pe niṣe lawọn olubi kan pa a, ti wọn si ju oku danu.

Kọmadaati Oluṣẹgun lawọn ti fa awọn afurasi naa le ileeṣẹ ọlọpaa lọwọ, ni ẹka teṣan too-geeti Ibadan, pẹlu ẹsibiiti eegun oku gbigbẹ naa, awọn si ṣi n baṣẹ lọ lati wa awọn yooku tọrọ yii kan lawaari.

Leave a Reply