Wọn ba oku Abayọmi nibi tawọn agbebọn pa a si l’Agbọwa-Akoko

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ọkunrin kan ti wọn porukọ rẹ ni Abayọmi Olukoju ni wọn ri oku rẹ nibi tawọn agbebọn pa a si lagbegbe Ajọwa Akoko, lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ ta a wa yii.
Ọkunrin ẹni ọdun mọkandinlaaadọta ọhun la gbọ pe wọn ba oku rẹ ninu agbara ẹjẹ pẹlu ọpọlọpọ oju ọta ibọn lara rẹ laarin oju ọna Ajọwa si Akunnu Akoko.
Gẹgẹ bi ohun ta a fidi rẹ mulẹ lati ẹnu araalu kan ta a forukọ bo laṣiiri, o ni ibi iṣẹ ni Abayọmi mi dagbere pe oun n lọ laaarọ ọjọ iṣẹlẹ naa nigba to n kuro niluu Ajọwa, nibi to fi ṣe ibugbe.

Ko sẹni to ti i le sọ ni pato asiko tawọn janduku agbebọn ọhun da ọkunrin naa lọna lori ọkada to gun kuro nile.
Awọn arinrin-ajo kan to n bọ lati Abuja ni wọn pada ri oku rẹ ninu agbara ẹjẹ, nibi ti wọn pa a si, ti wọn si sare lọọ fi ohun ti wọn ri to awọn ọlọpaa atawọn ṣọja to wa nitosi leti.
Abayọmi lo ni wọn ba oku rẹ ni ibi kan naa ti wọn pa awakọ bọọsi kan to n na Ajọwa si Abuja si ni nnkan bii oṣu kan sẹyin.
Oku ọhun lo si wa ni mọṣuari ileewosan ijọba ti wọn tọju rẹ si lasiko ta a n kọ iroyin yii lọwọ.

Agbẹnusọ fawọn eeyan agbegbe Akoko, Ọgbẹni Sọji Ogedemgbe, to ba wa sọrọ lori iṣẹlẹ ọhun ni ọsẹ tawọn agbebọn atawọn ajinigbe n ṣe lawọn ilu Akoko ti da ẹru ati jinnijinni ti ko ṣee fẹnu sọ sọkan awọn araalu.
Gbogbo awọn agbẹ to loko lawọn oju ọna tawọn ajinigbe ti n ṣoro bii agbọn lo ni wọn ti pa oko wọn ti nitori ibẹru.
Ogedemgbe ni ijọba ko ṣe daadaa to fawọn eeyan agbegbe naa pẹlu bi wọn ṣe kọ eti ikun si gbogbo ẹbẹ tawọn n bẹ latẹyinwa pe ki wọn ṣeto awọn ẹṣọ alaabo to pọ si agbegbe Akunnu-Ajọwa, latari bode Ondo ati Kogi tawọn ilu ọhun wa.
Ko ti i ju bii ọsẹ kan pere lọ nigba ti apapọ awọn ẹṣọ alaabo nipinlẹ Ondo fọ gbogbo inu aginju to yi agbegbe Akoko ka, nibi ti wọn ti fi pampẹ ofin gbe awọn ajinigbe bii mẹẹẹdọgbọn.

Leave a Reply