Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ileeṣẹ ọlopaa ipinlẹ Ọṣun ti bẹrẹ iwadii lori iku to pa ọmọkunrin ọlọkada kan, Ṣẹgun, lagbegbe Owode-Ẹdẹ.
ALAROYE gbọ pe ilu Owode-Ẹdẹ, ni Ṣẹgun n gbe pẹlu iya rẹ, nibẹ naa lo si ti maa n ṣiṣẹ ọkada. Ọdọ awọn to n gbe ọkada fun-un-yan pẹlu owo-ele lo ti gba ọkada to n gun, o si ku bii oṣu kan ko sanwo rẹ tan niṣẹlẹ ọhun ṣẹlẹ.
Oju-ọja Owode-Ẹdẹ, ni Ṣẹgun ti gbe awọn ọkunrin meji kan lọjọ kejila, oṣu Karun-un, ọdun yii, wọn si sọ fun un pe yoo ba awọn gbe baagi simẹnti lọ sibi ile kan tawọn n kọ lọwọ.
Lati ọjọ yii lawọn mọlẹbi ti foju kan Ṣẹgun gbẹyin, ko too di ọjọ Abamẹta, Satide, to kọja, iyẹn ogunjọ, oṣu Karun-un, ọdun yii, nigba ti obinrin kan lagbegbe Oke-Ayọ, ni Owode-Ẹdẹ, ṣakiyesi pe oorun buruku kan n jade latinu ile akọku kan.
Bayii lo yọju wonu ile naa, to si ri oku ọmọkunrin kan nibẹ. Bo ṣe figbe bọnu niyẹn, nigba ti wọn yẹ ẹ wo lo di Ṣẹgun ọlọkada ti wọn ti n wa.
Bayii lawọn eeyan bẹrẹ si i rọ lọ sibẹ, ti wọn si fi iṣẹlẹ naa to ọlọpaa leti. Aarọ ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Karun-un yii, lawọn ọlọpaa lọọ gbe oku rẹ.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni iwadii ti bẹrẹ lati mọ awọn ti wọn ṣiṣẹ ibi naa, ireti si wa pe laipẹ lọwọ yoo tẹ wọn.