Ki i ṣe ayẹwo dokita lo fidi ẹ mulẹ pe awọn ololufẹ meji, Emmanuel Oshiotu, ẹni ọdun mejilelọgbọn ati Amaka Okafor, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn tawọn eeyan ba oku wọn ni yara, mu Sniper ni wọn fi ku. Ṣugbọn nitori pe gbogbo eeyan to wọnu yara wọn lo ri oogun apakokoro to jẹ majele naa nitosi ni wọn ṣe fura pe ohun ti wọn gbe mu niyẹn.
Ọjọbọ, Tọsidee to kọja yii, lawọn araale ri oku awọn mejeeji ninu yara kan ti wọn n gbe, iyẹn lopopona Ojigbo, nitosi Effurun, nipinlẹ Delta.
Yatọ si Sniper, wọn ni wọn tun ri ọbẹ kan nitosi awọn mejeeji, bẹẹ ni oku wọn ko jinna sira wọn.
Araale wọn kan to ṣalaye iṣẹlẹ naa fawọn akọroyin, sọ pe laago marun-un idaji Ọjọbọ naa lawọn bẹrẹ si i gbọ ariwo Emmanuel, to n sọ pe kawọn eeyan waa gba oun, ki wọn ṣannu oun. O ni nigba tawọn ja ilẹkun wọle lawọn ba a to n pọ ifoofo lẹnu, bẹẹ ni Amaka to jẹ ololufẹ ẹ ti wọn jọ wa ninu yara naa ti ku ni tiẹ.
Wọn gbe wọn lọ sọsibitu Central, Warri, ṣugbọn awọn dokita sọ pe oku ni awọn ti wọn gbe wa naa, bi wọn ṣe taari wọn si mọṣuari niyẹn.
Ṣaaju ni wọn ni Emmanuel ti kọ awọn ọrọ kan soju opo ikanni Fesibuuku rẹ, nibi to ti ṣalaye pe oun n dojukọ awọn iṣoro kan, ati pe o ti su oun.
Ohun to n dojukọ ko yeeyan, ko si sẹni to mọ pe oun ati Amaka ti wọn ti jọ n gbe bii tọkọ-taya yoo di oku laipẹ rara.
Awọn ọlọpaa fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, wọn si ni iwadii awọn n tẹsiwaju.