Jamiu Abayọmi
Ọmọ ọkunrin kan iba ti fiku ṣefajẹ lọwọ awọn araadugbo Ilemba-Hausa, nipinlẹ Eko, latari bi wọn ṣe ba oku ọmọde kan lọwọ rẹ, ọpẹlọpẹ awọn ọlọpaa agbegbe naa ti wọn tete de sibi tawọn araadugbo ti fẹẹ maa ki i ni bẹndẹ, ti wọn si gba a kalẹ lowọ iku.
Ajọ akoroyinjọ ilẹ wa, News Agency of Nigeria (NAN), sọ lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹjọ, ọdun yii pe lọjọ Ẹti, Furaidee, oṣu Kẹjọ yii, niṣẹlẹ naa ṣẹlẹ lasiko ti ọkunrin yii fẹẹ lọọ ba ọrẹ rẹ ti ọmọ rẹ ku sin ọmọ naa, tawọn eeyan si ri oku ọmọ yii lọwọ. Ni wọn ba bẹrẹ si i dagi jọ fun un, ọpẹlọpẹ awọn ọlọpaa ti wọn gba a silẹ.
Ero gbogbo awọn araadugbo ti wọn ri ọmọ naa lọwọ rẹ ni pe afiniṣetutu-ọla ni, wọn ro pe niṣe lo ji ọmọ naa gbe, to si fẹ lọ lo o.
O ni, “Nigba ti a fi ọrọ po o nifun pọ ni teṣan wa lo sọ pe ọmọ naa ti n ṣaisan lati bii ọjọ mẹta seyin, ko too waa ku lọjọ naa, ati pe ile-iwosan loun ti n gbe e bọ.
O fi kun ọrọ rẹ pe awọn obi ọmọ naa lo ran ohun lati lọọ ba wọn sin in, ti awọn eeyan fi ro pe oniṣẹ-ibi loun.
Ọga ọlọpaa lawọn obi ọmọ naa ti wa sọdọ awọn, ti wọn si jẹrii gbe ọkunrin ti wọn fẹsun kan yii. Lẹyin aridaju yii ni ileeṣẹ ọlọpaa ni ki wọn maa lọ pẹlu oku ọmọ naa.